You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Angela Merkel ti Germany fún ìgbà èkejì, gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ lóde
Olootu ijọba orileede Germany Angela Merkel tun ti gbọn pẹpẹ nitagbanga fun igba ẹlẹkeeji.
Iṣẹlẹ to jọ mọ pe o n ka otutu yii ṣẹlẹ nibi ayẹyẹ kan to waye nilu Berlin tii ṣe olu ilu orileede Germany.
Fọnran fidio ṣe afihan bi Merkel tii ṣe kawọ mọra ti o si bẹrẹ si ni gbọn pẹpẹ nita gbangba. Lẹyin nkan bi iṣẹju meji ara rẹ da, ti o si pada wa bọwọ pẹlu Minisita tuntun feto idajọ lorileede naa, Christine Lambrecht.
Wọn gbe omi fun Merkel amọ o kọ lati mu u.
Ooru to mu pupọ ni Merkel lo ṣe okunfa gbigbọn pẹpẹ rẹ to waye kẹyin amọ lọtẹ yii, a gbọ pe aaye ti ayẹyẹ naa ti waye ko gbona pupọ.
Agbẹnusọ fun Merkel ni kokoko lara rẹ le ati pe yoo tẹsiwaju pẹlu irinajo rẹ lọ si orileede Japan.
Bi a ko ba gbagbẹ lasiko ti olootu ijọba Merkel n gba alejo Aarẹ Ukraine Volodymyr Zelensky lo kọkọ bẹrẹ si ni gbọn nita gbangba.
Ara rẹ pada balẹ lẹyin ti wọn fun un ni omi mu.