Ọba Thailand Vajiralongkorn sọ ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ di olorí láàfin

Ọba orile-ede Thailand ti jẹwọ ipo rẹ gẹgẹ bi alaṣẹ aṣeyiowu pẹlu bi o ti ṣe sọ ẹsọ rẹ di olori ti o si sọ di ayaba laafin.

Atẹjade kan lati aafin ọba naa lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Ikede iyalẹnu yi jẹyọ pẹlu bi ayẹyẹ iwuye alaragbayida ti wọn yoo ṣe ti ṣe ku ọsẹ kan.

Ọba Maha Vajiralongkorn,ti ṣe ẹni ọdun mẹ́rìndínláàdọ́rindi ba lẹyin ti baba rẹ ti awọn ara ilu fẹran gidi gaan papoda lọdun 2016.

O ti kọ iyawo mta silẹ saaju asiko yi ti o si bi ọmọ meje.

Gẹgẹ bi atjade naa ti ṣe sọ, o ni ọba Vajiralongkorn " ti pinu lati mu agbega ba ọgagun Suthida Vajiralongkorn Na Ayudhya, to jẹ ẹni ayo rẹ si ipo olori ti yoo si di ipo yi mu gẹgẹ bi olori laafin''

O ti pẹ ti awọn ara ilu ti mọ olori Suthida gẹgẹ bi wọlewọde Oba bo ti lẹjẹ wi pe wọn ko sọ sita pe awọn n fẹ ara wọn.

Niṣe ni wọn fi fọnran fidio igbeyawo wn han lori ẹrọ amohunmaworan orile-ede Thailand lọjọru nibi ti awọn ori ade ati ilẹkẹ peju sibẹ.

Lọdun 2014 ni Ọba Vajiralongkorn yan Suthida Tidjai, to figba kan jẹ oṣiṣẹ ile iṣẹ ọkọ ofurufu si ipo igbakeji olori awọn ẹsọ Ọba.

Nigba ti yoo fi di ọdun 2016, o fi oye ọgagun daa lọla.

Ọba to jẹ saaju Ọba Vajiralongkorn,Ọba Bhumibol Adulyadej lo àádọ́rin ọdun lori itẹ eyi to mu jẹ Ọba to pe lori oye julọ lagbaye.

O waja lọdun 2016.