Brexit: Ilé làbọ̀ ìsinmi oko fọ́mọ Yorùbá nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Ọgọọrọ eeyan lo ti n sọrọ lori bi Olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Theresa May ṣe mori bọ l'Ọjọru nigba ti ile aṣofin fẹ yọọ nipo lori ọrọ Brexit.

Ọgbẹni Kayode Ogundamisi, ọmọbibi orilẹ-ede Naijiria to fi Ilẹ Gẹẹsi ṣe ibugbe ba BBC Yoruba sọrọ, o ni ero t'oun ni pẹ ju gbogbo rẹ lọ, ile labọ isinmi oko boya Ilẹ Gẹẹsi kuro ninu ajọ EU tabi wọn o kuro nibẹ.

O ṣalaye pe ọpọ ọmọbibi Naijiria ti wọn n gbe ni Ilu Ọba ko ba ti wa nibẹ to ba jẹ pe nnkan fararọ lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Ogundamisi fikun ọrọ rẹ pe ọpọ eeyan to wa lati ilẹ Afirika ni ireti pe iṣẹ yoo sìn wọn bọ̀ ti Olootu ijọba May ba ṣe aṣeyọri pẹlu eto Brexit, nitori awọn eeyan miran ti wọn wa ṣiṣẹ nilẹ Gẹeṣi yoo pada sorilẹ-ede abinibi wọn.

O ni nibayii, awọn oyinbo alawọ funfun lati orilẹ-ede miran ni wọn kọkọ maa n riṣẹ ki awọn alawọdudu to ri, ṣugbọn o sọ pe ko si ẹni to le sọ pato bi gbogbo nnkan ṣe maa ri ti Ilẹ Gẹeṣi ba fi ajọ EU silẹ.

Ọgbẹni Ogundamisi ko sai ṣalaye pe , awọn ọmọ Ilẹ Gẹẹsi n jẹ anfani to pọ gan bi orilẹede naa si ti n ba ajọ EU ṣe papọ.

O ni awọn ẹni to ba jẹ ọmọbibi Ilẹ Gẹẹsi tabi ẹni to ba ni iwe igbelu lọwọ lanfani lati lọ gbe tabi lọ ile iwe lorilẹ-ede alawọfunfun ni wọn igba ti Ilẹ Gẹẹsi si wa pẹlu ajọ EU.

Ṣugbọn gbogbo anfani yii ni yoo dopin gbara ti Ilẹ Gẹẹsi ba ti fi ajọ EU silẹ.