You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹgbẹ̀run kan náírà ni obì ní Brazil?
Iroyin kan sọ pe obì tita ti di ohun amuṣọrọ bayii l'orilẹede Brazil.
Iroyin naa fi idi rẹ mulẹ pe wọn n ta obi kan ṣoṣo ni Dọla meji, eyi to fẹ ẹ to ẹgbẹrun kan Naira, nitori pe ojoojumọ ni ẹsin abalaye ẹya Yoruba n gbilẹ si ni Brazil.
Itakun ayelujara NewsmakersNG jabọ pe iwadi oun fihan pe iye ti wọn ta obi kan niṣe pẹlu iru obi to ba jẹ, ati wi pe awọn oniṣowo obi fi mulẹ pe iye to kere ju ti wọn n ta obi nile itaja tabi ni ojubọ ni Brazil bẹrẹ lati Dọla kan.
Ọkan lara awọn ọmọ Yoruba to n gbe l'orilẹede Brazil, to tun jẹ aṣoju Ọọni Ile Ifẹ ni Brazil, Ajoyẹmi Ọṣunlẹyẹ, sọ fun akọroyin BBC Yoruba pe bi wọn ṣe n lo obi fun oriṣiriṣi nkan ni orilẹede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba, naa ni wọn n lo o ni Brazil.
Ati wi pe ''orilẹede Naijiria ni wọn ti n ko ọpọlọpọ obi ti wọn n jẹ ni Brazil.
Lara nkan ti wọn n lo o fun ni jijẹ, nkan alejo, nibi ayẹyẹ igbeyawo, ikomọ, tabi isinku lati fi ṣadura.
Bakan naa ni awọn babalawo wọn, ti wọn n pe ni Babalorixá tun maa n lo lati fi dá ifá gẹgẹ bi ẹya Yoruba ṣe n ṣe.
Awọn ọmọ orilẹede Brazil kan tilẹ gbagbọ wi pe ilẹ Yoruba ni orisun wọn. Laipẹ yii ni awọn kan lara wọn wa si orilẹede Naijiria lati ṣe eto ti yoo fun wọn ni anfaani lati maa pe ilẹ Yoruba ni orisun wọn.
Oriṣiriṣi obì lo wa. Awọn bi i obì abata, obì gbanja, ati bẹẹbẹ lọ.
Eyi ṣeeṣe ko jẹ ọna okoowo mi niyii fun awọn to ba n wa òwò ti wọn le ṣe. Wọn le maa ka ko obi lati Naijiria lọ si orilẹede Brazil.
Ṣugbọn, ki o to o bẹrẹ okoowo kiko obi lọ si Brazil, o nilo lati mọ wi pe oriṣiriṣi nkan lo so mọ Dọla meji ti o o fẹ̀ ta obi kan.
- Owó ori to o san ni papakọ ofurufu tabi ibudokọ ori omi
- Owó sisan fun ajọ aṣọbode ni Naijiria
- Owó o fifi ẹrù ranṣẹ
- Owó to o san fun
- Owó sisan fun ajọ aṣọbode l'orilẹede Brazil
- Ati owó ori sisan fun ijọba orilẹede naa.