Chris Daizell: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bú mí, wọ́n ní mo dàbí ọ̀daràn

"Igbakuugba ti mo ba n wẹ, ti mo ba si ri alafo ni ara mi laisi Tattoo nibẹ, o maa n bi mi ninu - Mo gbọdọ lọ fi Tattoo bo."

Chris Dalzell gba pe sise ọsọ ara pẹlu Tattoo ti di baraku fun oun.

To ba si n wa aaye kan ninu ara rẹ, ti wọn ko ya Tattoo si, o tiraka diẹ ko to lee ri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Loju awọn eeyan miran, Chris, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan n gbe igbe aye lasan ni, amọ ko yatọ si ère isẹ ọna ti wọn gbẹ silẹ, eyi ti wọn fi aworan tattoo bo lara lati ori de ẹsẹ ni awọn aworan to fa ni mọra.

Sugbọn loju Jessica, ọmọdebinrin ti Chris bi, baba si ni ọkunrin naa jẹ, amọ loju awọn ara ita, oju "Iwin" tabi "o lee jẹ́ ọdaran" ni wọn fi n wo.

"Awọn eeyan kan ni ki wọn mu ọmọ mi kuro lọdọ mi, ti wọn ko si gbọdọ gba mi laaye lati lọ si ileewe jẹleosinmi rẹ nitori bi mo se ri tabi pe mo dabi ẹni to n fi aake pa eniyan." Chris lo sọ fun BBC bẹẹ.

"Awọn eeyan to ba ri mi loju titi yoo rin tọ mi wa, ti wọn yoo si sọ fun mi pe mo da bii ọdaran."

Chris wa fi idi rẹ mulẹ pe to ba jẹ pe lootọ ni oun huwa ọdaran, ko lee pẹ rara ti ẹnikan yoo fi da oun mọ.

Chris ni itara fun itọju ara rẹ lati kekere sugbọn lẹnu lọọlọ yii, ọna ara ọtọ lo gba tọju awọ ara rẹ. O si lọ ya aworan tattoo naa lati fi pa ironu rẹ lori ọmọ rẹ to n se aisan ni.

"Ara Jessica ko dape lati igba ti wọn ti bi. Ko ye mi ọna ti maa gbe gba, to si n ka mi lara pe n ko lee mu irora kuro lara ọmọ mi.

Bi o tilẹ jẹ pe afojusun to ga ju laye ti mo fẹ ni lati fi aworan tattoo bo gbogbo ara mi, amọ aisan ọmọ mi lo jẹ ko ya kiakia lati se bẹẹ."

"Mo ro pe ọna to dara lati koju aisan ọmọ mi ni ki n lọ ya Tattoo, eyi si ti ran mi lọwọ. Mo fẹ ki ọmọ mi mọ mi bayii lati kekere rẹ."

"Ti mo ba fi àwọ̀n boju lati dẹru ba Jessica, sibẹ yoo fi ọwọ kan oju mi, yoo si fẹnu ko mi lẹnu. O mọ bi awọ ara mi ti ri, o si mọ pe emi ni baba rẹ."

"Emi kii se iru eeyan tẹ ro pe mo jẹ. Ẹ gba mi gbọ, n ko ronu jinlẹ rara lori oju tawọn ara ilu yoo fi wo mi, ki n to lọ se tattoo yii."

Amọ Chris ni oun fẹ ki awujọ gba oun bi oun ti ri. O ni oun mọ idi ti wọn se n se idajọ oun, nitori pe wọn ko ri oun ni ojoojumọ ni lati ni oye iru ẹni ti oun jẹ, ki wọn si tẹwọgba oun.