You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdájọ́ ikú: Ààdọ́sàn-án orílẹ̀-èdè ló ti fòfin de ìdájọ́ ìpànìyàn
Akọwe Agba fun Ajọ Isọkan Agbaye (United Nations), António Guterres ti gbẹ oriyin fun awọn orilẹede to ti fofin de idajọ iku lorilẹede wọn, lasiko to n sami ẹyẹ ayajọ ọjọ to fofin de idajọ iku lagbaye.
Gutterres sọ eyi lasiko to n fi iroyin bi nkan se n lọ lagbaye to Igbimọ Ajọ Agbaye to n risi ẹtọ ọmọniyan lagbaye leti.
O sọ wi pe orilẹede aadọsan lo ti fofin de idajọ iku tabi ti wọn ti wọgile ọna isekupani yiii, nigbati awọn orilẹede miran ti se ofin to n gbero lati fagile ise naa, ti wọn ko si se idajọ iku ni ọdun mẹwa.
Àwọn ìlú tó ti fòpin sí ìsekúpani
Ajọ Isọkan Agbaye naa ni awọn iroyin lati ọwọ awọn orilẹede naa, awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ati awọn to fi ọju gan ni awọn isẹlẹ naa.
Amọ, Ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan, Amnesty International sọ wi pe, orilẹede mejilelogoje lo ti fi ọwọ osi juwe ile si sise idajọ iku, ati wi pe, orilẹede mẹtalelọgbọn lo ti se idajọ iku laarin ọdun marun.
Ìsekúpani ní àgbáyé
Orilẹede mẹrin bii Saudi Arabia, Iraq, Pakistan ati Iran lo ti kopa ninu idajọ iku ni ọdun 2017, pẹ̀lú orilẹede China ti wọn ko yẹ ki iye rẹ han si ita.
Ajo ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye sọ wi pe, awọn ọna ti wọn n gba pa eniyan ni ki wọn bẹ ori wọn, ki wọn so okun mọ wọn lọrun titi ẹmi yoo fi bọ lara wọn, ati fifun eniyan ni abẹrẹ iku, pẹlu yi yin wọn ni ibọn.
Awọn orilẹede to se idajọ iku ni ọdun 2013 si 2017:
- Afghanistan
- Bahrain
- Bangladesh
- Belarus
- Botswana
- Chad
- China
- Egypt
- Equatorial Guinea
- India
- Indonesia
- Iran
- Iraq
- Japan
- Jordan
- Kuwait
- Malaysia
- Nigeria
- North Korea
- Oman
- Pakistan
- Palestine
- Saudi Arabia
- Singapore
- Somalia
- South Sudan
- Sudan
- Taiwan
- Thailand (2018)
- United Arab Emirates
- USA
- Vietnam
- Yemen.
Amọ, Ajọ Amnesty International ko le e sọ pato, boya orilẹede ti ogun ti n sẹlẹ lọwọlọwọ bii Libya ati Syria n se idajọ iku fun awọn eniyan.
Awọn orilẹede to se idajọ iku ni ọdun 2013 si 2017
Awọn orilẹede mọkandinlogun ni ko se idajọ iku lasiko ti ko ti le jẹ eewọ.
- Antigua and Barbuda
- Bahamas
- Barbados
- Belize
- Comoros
- Cuba
- Democratic Republic of the Congo
- Dominica
- Ethiopia
- Gambia
- Guyana
- Jamaica
- Lebanon
- Lesotho
- Qatar
- Saint Kitts ati Nevis
- Saint Lucia
- Saint Vincent ati the Grenadines
- Trinidad ati Tobago
- Uganda
- Zimbabwe.