Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, wọ́n ri àwọn ọdọ Thailand to há sínú ilẹ̀

Awọn òmọ̀wé ti ṣe awari awọn ọdọkunrin mejila ati ọkunrin kan ti o n kọ won ni erebọọlu ti wọn ha sinu iho ilẹ lati bíí ọjọ́ mẹwàá ni orilẹede Thailand bayi.

Iroyin naa ti sọ orileẹ̀ede naa sinu ajọyọ bayii bi wọn ti ṣe n gbadura ki awọn ọmọ naa ṣi wa laaye nigba ti wọn ba maa ri wọn.

Awọn ọmọ mejila naa ati akọnimọọgba wọn has sinu iho (cave) Tham Luang ni agbegbe Chiang Rai ni orilẹede naa.

Nigba ti iroyin naa kan pe awọn òmọ̀wé meji to kọkọ wọ inu iho naa ti ri awọn ọmọ naa laaye, ṣe ni idile wọn ti wọn foju sọna lẹnu iho naa bu si ajọyọ.

Sugbọn ni bayii, awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri ni bi wọn yoo ṣe gbe wọn sita ni eyi ti o wa lagbara ju nitori pe omi ati pọtọpọtọ to wa ninu iho naa pọ.

Nigba ti wọn ri awọn ọmọ naa, wọn beere igba ti wọn yoo le gbe wọn jade lati inu iho naa, awọn omuwe meji to wọ inu iho naa sọ fun wọn pe yoo ṣi ṣe diẹ. Lẹyin naa ni awọn ọmọ naa ni ebi ti fẹ pa awọn ku o.

Àwọn ọdọ naa lo jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Moo Pa. Ọjọ ori wọn jẹ mọkanla si mẹrindinlogun.

Ọjo kẹtalelogun oṣu kẹfa ni awọn ati akọnimọọgba wọn, Ekkapol Janthawong, lọ ṣere ninu iho Tham Luang ti wọn ko si le jade mọ.

Bí ẹgbẹrun eniyan lati China, Myanmar, Laos, Australia, Amerika ati Ilẹ Gẹẹsi ni a gbọ pe o n kopa ninu igbiyanju lati yọ awọn ọdọ naa ninu ewu ti wọn wa.