Headline Inflation for July 2022: Ọ̀wọ́ngógó ọjà ní Nàìjíríà gbéra dé ìdá 19.6%, wo ohun tó túmọ sí fáráàlú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ aṣeṣiro lorileede Naijiria National Bureau of Statistics ti gbe iwadii jade lori ọwọngogo nkan foṣu Keje ọdun yi.

Ninu akọsilẹ nkan ti wọn gbe jade, odinwọn iye ti ọwọngogo ọja fi le si ti di 19.64%.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, iye yi lo ga jul niye ọwọngogo ọja lati nkan bi ọdun mẹtadinlogun ṣẹyin.

Iye yi lọ soke ju ti oṣu Kẹfa to jẹ 18.6%

Iroyin tuntun taa gbọ yi jẹ afihan iye owo ọja ti eeyan kankan n ra eyi ti NBS gbe jade.

Onimọ kan nipa ọrọ to ni'se pẹlu ọrọ aje ṣọ pe pẹlu ohun to jade yi,inu wahala nla ni Naijiria wa.

'Nkan ti wa doju ẹ bayi'

Onimọ Muda Yusuf to jẹ ọgba agba ajọ to n ṣe igbelarugẹ idokowo aladani sọ fun BBC pe ṣoki ohun ti eyi tunmọ si ni pe nkan ti gbowo lori.

O ni awọn ti ko rọwọ họri yoo tunbọ maa koju inira ni tori ọwọngogo ounjẹ.

Onimọ yi sọ pe pataki esi ti wọn gbe jade yi ni kawọn eeyan fi mọ pe nkan ko rọgbọ mọ.

''Iye owo ounjẹ ti lekun ni ilọpo meji. Ẹ mọ boṣe n ri tawọn eeyan ba n tiraka lati ri ounjẹ jẹ''

Nkan ti ida 19.64% n sọ fun wa ni pe nkan ti kja afẹnusọ.

Ki lo fa ọwọngogo yi

Muda Yusuf ṣalaye awọn nkan to lo ṣokunfa ọwọngogo nkan yi.

Ninu re la ti ri

  • Aabo to mẹhẹ
  • ọwọngogo owo ina ati awọn nkan ti wọn fi n pese ounjẹ ati awọn ọja miran
  • Iye taa n paarọ Naira si dọla
  • Bibanki apapọ CBN ṣe n fi owo di gbese

O tẹsiwaju alaye rẹ pe ''Aabo to mẹhẹ ko jẹ ki awọn eeyan lọ dako. Pupọ awn to yẹ ko wa loko ti n fori pamọ lawọn ibudo ogunlende.Iye owo taa n na lati fi san owo ina mọnamọna disuu ati nkan mi ta fi n peelo awọn ounjẹ naa da kun wahala yi''

O ni ''iye taa fi n parọ Naira si dọla lonii naa jẹ ipenija to n mu ki ọwọngogo ba awọn nkan taa n lo ni Naijiria.''

Ki ni ijọba le ṣe?

Ninu amọran to gba ijọba Onimọ yi sọ pe ijọba ni lati foju sunukun wo ibi ti ọrọ aje Naijiria de duro bayi.

Muda Yusuf fi kun pe ''Ko jọ pe ijọba n gbe igbesẹ kankan.Igbimọ alakosọ ọrọ aje igbakeji aarẹ lo n lewaju rẹ. Koda ọga igbimọ yi naa kan wa nibẹ ni. Ko ṣe nkankan''

Ki ijọba ko awọn to mọ nipa ọrọ aje lo yẹ. Kii ṣe nkan to ruju rara.Naijiria lawọn ọlọpọlọ pipe to le wa ojutu si ọrọ yi.

Ohun ti onimọ yi sọ ree lori ọna ti Naijiria fi le yanju nkan to wa nilẹ.

Ni pataki o sọ pe ki ijọba uyanju ọrọ aabo to mẹhẹ ṣaaju ohun gbogbo.