You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
International Women's Day: Kí ni pàtàkì àyájọ́ àwọn obìnrin lágbáyé fún Áfíríkà?
Lọdọọdun ni ajọ iṣọkan agbaye, UN maa n ya ọjọ kẹjọ oṣu kẹta sọtọ lati ṣajọyọ ayaọ ẹtọ awọn obinrin lagbaye ati lati yanana awọn ipenija ti wọn ṣi n koju paapaajulọ pẹlu idẹyẹsi wọn ni gbogbo ẹka mọniyan.
"Ilana aparokan ko gajukan l fun taktabo fun ọjọ ọla to yanranti" ni akori ajọyọ tdun yii eyi ti ajọ UN ya sọt bii ayajọ awọn obinrin lagbaye, International Women's Day (IWD).
Ki nidi ti wọn fi mu akori yii?
Dokita Maxime Houinato, adari ọrọ awọn obinrin fun ajọ UN lẹkun Ila oorun ati gusu Afrika fi to BBC leti pe, " fifọnrere pataki idgba taktabo lori rọ bii wahala oju ọjọ ati ajalu yoo mu ki adinku ba ipenija to le ju to n waye lagbaye."
O fi kun un pe, "Awọn obinrin atawọn ọmọbinrin ni wahala oju ọjọ n ba finra jul lagbaye."
Alaye ti ajọ to n ri si ọrọ igbayegbadun awọn obinrin, UN Women fi sita loju opo ayelujara rẹ sọ pe fun apẹrẹ "ida marundinlọgọrun iku to waye ni orilẹede Solomon Islands nipasẹ ikun omi lo jẹ awọn obinrin, ida marundinlọgọta awọn ti ilẹ riri pa ni Nepal ldun 2015 lo jẹ obinrin, ida mọkandinlọgọta awọn ti iji lile sọ di alairile gbe ni Malawi lọdun 2019 lo jẹ Obinrin."
Bawo ni ayajọ awọn obinrin ṣe waye?
Ipe ati ijijangbara awọn oṣiṣẹ lọdun 1908 lo fa ayajọ̀ awọn obinrin lagbaye, ki ajọ United Nations to wa kede rẹ ni gbangba walia lọdun 1975.
Ni ọdun 1908, o le lẹgbẹrun marundinlogun awọn obinrin to wọde kaakiri ilu New York city lati beere fun adinku iye wakati tawọn obinrin n lo lẹnu iṣẹ, agbega owo oṣu pẹlu ẹtọ lati dibo.
Ẹgbẹ oṣelu The Socialist Party of America lo wa kede ayajọ awọn obinrin lorilẹede Amẹrika fun igba akọkọ lọdun to tẹlee.
Gbajumọ ọmọ orilẹede Germany kan to jẹ ajafẹtọ obinrin to tun jẹ ogunnagbongbo lara awọn to nifẹ si ilana iṣejọba Mraxism, Clara Zetkin wa lara awọn eeyan to kọkọ ja fun iyasọtọ ọjọ kan fun awọn obinrin lagbaye gẹgẹbi ti orilẹede Amẹrika.
Awọn ọgọrun obinrin lati orilẹede mẹtadinlogun lagbaye darapọ mọ Zetkin nibi ipade apero kan fawọn obinrin to n ṣiṣẹ to waye nilu Copenhagen lorilẹede Denmark lọdun 1910.
Nibi ipade naa ni wọn ti fẹnuko pẹlu amọran Zetkin pe bẹrẹ pẹlu dun to tẹle ki ayajọ obinrin maa waye lorilẹede Austria, Denmark, Germany ati Switzerland bi o tilẹ jẹ pe ko mu ọjọkan pato wa fun ṣiṣe ajọyọ ayajọ naa.
Bawo wa ni nilẹ Afirika?
Orilede meje pere lo ya ọjọ awọn obinrin sọtọ gẹgẹ bi jọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Awọn orilẹede naa ni, Eritrea, fun ipa ti awọn obinrin ko gẹgẹ bi jagunjagunlasikoọdun mẹwaa ti orilẹede naa fi jijangbara fun ominra.
Awọn orilẹede ilẹ Afirika yoku to ti gba ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun gẹgẹbi ayajọ awọn obinrin ni Angola, Burkina Faso, Guinea-Bissau, Sierra Leone and Uganda ati Zambia.
Lorilẹede Madagascar, ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ lọjọ naa fun awọn obinrin nikan.
Awọn orilẹede miran ni Afirika ni ọjọ ọtọ ti wọn mu fun ayajọ awọn obinrin-Orilẹede South Africa nitirẹ mu ọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ ti wọn si yan gẹgẹbi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni iranti ẹgbẹrun lọna ogun awọn obinrin ti wọn wde ni ọjọ naa lọdun 1956 lati fẹhonu han tako awọn ilakalẹ ẹlẹyamẹya ijọba alawọfunfun nibẹ nigba naa.
Fun afikun si eyi,ajọ iṣọkan orilẹede Afirika, AU ti kede jọ kọkanlelọgbọn oṣu keje gẹgẹ bi ayajọ awọn obinrin nilẹ Afirika.
AU ni ọjọ naa nfojusun si "ifidimulẹ ati iduroṣinṣin" awọn obinrin lọna "ati gba ominira oṣelu fun Afirika ati imugbooro igbesẹigbayegbadun araalu ati ọrọ aje lorilẹ Afrika."