Obasanjo bẹ Oloye Lekan Balogun, Olubadan tuntun wo, mọ́ínmọ́ín àti ògì ló fi ṣinu níbẹ́

Obasanjo bẹ Olubadan tuntun wo, mọ́ínmọ́ín àti ògì ló fi ṣinu níbẹ́

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti lọ ṣe abẹwo k'ade pẹ lori si ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii Olubadan ti ilẹ Ibadan, oloye Lekan Balogun ni ile rẹ to wa lagbegbe Alarere nilu Ibadan.

Oloye Ọbasanjọ sọ ọ ninu ọrọ ikini ku oriire rẹ pe yiyan ti wọn yan Oloye Balogun gẹgẹ bii Olubadan kejilelogoji kii ṣe iṣẹ eniyan bikoṣe iṣẹ Eleduwa.

O ni igbagbọ oun ni pe pẹlu iriri gbogbo ti Oloye Lekan Balogun ti ni, awọn iyatọ idagbasoke yoo tete maa fara han nilu Ibadan lasiko rẹ.

Ki ni wọn fi ṣe Ọbasanjọ lalejo?

Lẹyin ijiroro to mu ọpọlọpọ ẹrin dani, Oloye Lekan Balogun ati Oloye Oluṣẹgun Obasanjọ joko ti ogi ati mọinmọin lati fi panu.

Irinajo awọn eekan mejeeji yii ti bẹrẹ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin paapaa lasiko ti iṣejọba alagbada to wa lode ti bẹrẹ ninu eyi ti awọn mejeeji ti jumọ jẹ eekan ẹgbẹ oṣelu PDP.

Nigba wo ni Olubadan tẹlẹ gbesẹ?

Ni ọjọ keji oṣu kini ọdun 2022 ni olubadan ana, Ọba Saliu Adetunji Ahe ogugunisọ I waja lẹyin aisan ranpẹ.

Lati igba yii wa ni oniruru ariyanjiyan lori boya oye tọ si Oloye Balogun tabi ko tọ sii bẹrẹ; paapaajulọ pẹlu ipa to ko laarin awọn oloye Ibadan to lọ tẹri gba ade lọwọ gomina ana n'ipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.

Eyi tako aṣẹ Olubadan nigba naa pe ki eyikeyi awọn oloye Ibadan maṣe gba ade naa nitori ko ba ilana oye jijẹ ilẹ Ibadan mu.

Ọrọ naa de ile ẹjọ to pada di awuyewuye nla, eyi lo si faa ti ọpọ ọmọbibi ilẹ Ibadan fi fẹhonu han pe eyikeyi awọn oloye to gb'ade naa ko lee jọba Ibadan mọ nitori ko si ni ilana oye jijẹ nilu Ibadan pe ki eeyan gba ade lẹẹmeji.

Gomina ipinlẹ Ọyọ to da si ọrọ naa lo ba wọn yanju rẹ pe ki awọn oloye ti ọrọ kan kọkọ lọ gbe ade wọn silẹ ki wọn si gbe ẹjọ gbogbo ti wọn ba pe kuro nile ẹjọ.

Nigba wo ni Olubadan tuntun yoo gba ade?

Lẹyin ti wọn ṣe gbogbo eyi tan ni wọn fi orukọ Lekan Balogun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi ọmọ oye tuntun.

Ni ọjọ Aje ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2022 ni gomina Makinde, ninu atejade kan ti agbẹnusọ rẹ Taiwo Adisa fi sita, kede Oloye Lekan Balogun, gẹgẹ bii Olubadan tuntun.

Lẹyin eyi lawọn igbimọ agbaoye ilẹ Ibadan wa kede ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2022 gẹgẹ bi ọjọ igbade oloye Lekan Balogun, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin gẹgẹ bi Olubadan tuntun.