Aisha Buhari pè fún fífi àyè gba àwọn obìnrin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin

Aya Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Aisha Buhari lónìí ọjọ́rú ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kejì, ọdún 2022 lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ láti pé fún fífi àyè gba àwọn obìnrin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ju bó ti wà lọ.

Aisha Buhari ń pè fún ṣíṣe àtúnṣe sí ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí láti fi àyè gba kí iye àyè kan wà pàtó fún àwọn obìnrin ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀.

Aisha Buhari ló kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà pẹ̀lú Mínísítà fọ̀rọ̀ obìnrin, Pauline Tallen àti Mínísítà fétò ìsúná àti ọ̀rọ̀ ààtò ìlú, Zainab Ahmed.

Kíni Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà sọ?

Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Ahmad Lawan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí igbákejì rẹ̀, Ovie Omo-Agege tẹ́ pẹpẹ àbá aya Ààrẹ síwájú ilé ní àbá náà ń pè fún àlékún sí àwọn aṣòfin obìnrin ní àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin méjéèjì.

Lawan ní àbẹ̀wò Aisha Buhari ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè yìí bó ṣe ní ipa àwọn obìnrin kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ṣíṣe àwọn òfin tí yóò mú ìlọsíwájú bá orílẹ̀ èdè.

Ó fi kun pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí akọ̀mọ̀nà rẹ̀ jẹ́ Ìṣọ̀kan àti Ìgbàgbọ́, Àláfíà àti Ìlọsíwájú, ó pọn dandan kí gbogbo ènìyàn sa ipá wọn láti mú orílẹ̀ èdè yìí gòkè àgbà.

Bákan náà ló fi dá Aisha Buhari lójú pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́kẹ̀sán yóò ri dájú àtúnṣe ìwé òfin Nàìjíríà fàyè gbà kí ipò tí àwọn obìnrin yóò dímù nínú òṣèlú bá iye àwọn obìnrin tó wà ní ìlú mu.

Femi Gbajabiamila náà ṣèlérí àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin

Bí ilé ìgbimọ̀ aṣojúṣòfin, Abẹnugan ilé Femi Gbajabiamila ní Aisha Buhari wá sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà láti fi àtìlẹyìn rẹ̀ hàn sí àwọn àtúnṣe tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin.

Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kẹta ní àwọn aṣòfin náà yóò dìbò lórí àwọn àtúnṣe tí wọ́n fẹ́ ṣe sí ìwé òfin.