You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Small Mummy: Ẹ̀bún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó ńlá ni wọn fi sàmì ọjọ́ ìbí ọdún kẹwàá ọmọdé aláwàdà
Yoruba ni ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu nitori kekere ni ẹda ti n yan ipa ọna ti yoo tọ nile aye.
Bi ọrọ se ri gẹlẹ ree pẹlu ọdọmọde, ọmọ ọdun mẹwa kan to jẹ alawada loju opo ayelujara Instagram, Ashafa Salamot, ti ọpọ eeyan mọ si Small Mummy.
Ọdọmọde yii si ni ọpọ eeyan mọ pupọ loju opo Facebook ati Instagram fun awọn ere ati ọrọ agbalagba to maa n fi se awada.
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kóo mọ̀ nípá ọmọ ọdún mẹ́wàá Emmanuella tó kọ́ ilé ńlá fún ìyá rẹ̀
- Òṣìṣẹ́ ológun Navy ni mí àmọ́ àwàdà ayélujára ló sọ mí di olókìkí - Cute Abiola
- Ọdún mẹ́ta gbáko ni mo fí ṣé ìgbáradì láti fi di "National Chess Master" -Tanitoluwa
- Ọ̀nà mi dàrú nígbà tí wọ́n lé mi ní Fáṣitì Ilorin, ọpẹ́ ádúrótì ìyá mí - Agba Inaki
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ti wọn fi ń lọ̀ mí lágbo àmúlùúdùn ni ìṣòro kan tí mo ní - Lizzy Jay ọmọ Ibadan
- Tí òṣèré tíátà yóò fi kú, eré ni wọn yóò ló ń ṣe - Ibrahim Chatta
- "Ma a pa ara mi si Cute Abiola lọrun bo ṣe já mi silẹ tori afẹsọna miran"
Small Mummy jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye fun ọjọ ibi rẹ:
Small Mummy, ẹni to bẹrẹ awada lori ayelujara ko to pe ọmọ ọdun meje lo ti pe ọmọ ọdun mẹwaa bayii.
Ọpọ ojo ẹbun lo ti wa n rọ si ọdọ ọdọmọde adẹrinposonu naa, eyi ti awọn ololufẹ rẹ n fun.
Amọ pabambari ẹbun to tii jọju julọ ti Small Mummy yoo gba fun ajọyọ ọdun kẹwa to de ile aye naa ni ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye kan.
Awọn ololufẹ rẹ si lo da owow jọ lati ra ọkọ ayọkẹlẹ alawọ funfun naa, tii se alawọ Toyota Sienna, to le gba ero bii meje fun ọdọmọde naa.
Ko tan sibẹ o, awọn eeyan naa tun gba nọmba adanikanlo si ara ọkọ naa, eyi ti wọn kọ Small Mummy si lara.
Ikede naa ti Small Mummy se soju opo Instagram rẹ lo mu inu ọpọ olulufẹ rẹ dun.
Eyi si lo mu Small Mummy di ọdọmọde miran ti yoo gbe ohun ribiribi se lati ipasẹ awada sise ni ori ayelujara.
Ọpọ ololufẹ Small Mummy si lo ti n ki adẹrinposonu naa ku oriire nipa ọkọ ayọkẹlẹ naa.
Omi bọ loju mi nigba ti mo gba ẹbun mọto ayọkẹlẹ:
Small Mummy nigba to n kede ẹbun ọkọ tuntun naa yin Oluwa logo pe o ka oun ku ara awọn eeyan to n lo mọto lati kekere.
O ni "Alihamudullilahi, O seun Jesu, Oluwa o se o.
Omije bọ ni oju mi nigba ti mo n kọ ọrọ yii, mo si n dupẹ lọwọ Ọlọrun, ẹni to ti n ba mi se lati ẹyin wa, ti ko si tun ni dawọ duro.
Gbogbo awọn eeyan to si da owo jọ lati ra mọto yii fun mi gẹgẹ bii ẹbun ati awọn eeyan ti yoo tun maa da owo jọ lati ra epo sinu rẹ, ko ni se alaini ohun to dara laelae."
Small Mummy tun wa ki Manija rẹ to n sisẹ tọsan toru lati ri daju pe isẹ iransẹ ori ayelujara to dawọ le yọri si rere.
O ni Ọlọrun yoo san ni ẹsan rere pupọ, to si tun fi ẹmi imoore rẹ han si gbogbo eeyan.
Small Mummy wa seleri pe oun yoo tubọ maa mu ki ori awọn ololufẹ oun wu si nipa oun atawọn awada ti yoo maa se.
Ta ni Ashafat Salamot, to tun n jẹ Small Mummy:
Small Mummy ni alawada ori ayelujara to maa n se bii olori ijọ Ọlọrun lobinrin.
Ede Yoruba da lẹnu rẹ, to si maa n sọrọ bii agbalagba.
Oun ni ọmọbinrin kan soso laarin ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ bi ati abikẹyin ninu ẹbi naa.
Ko si ti pe ọmọ ọdun meje to ti bẹrẹ awada sise ni ori ayelujara, to si ni awọn ẹgbọn oun to jẹ ọkunrin lo fun oun ni iwuri ati imisi awada sise.
Small Mummy yii si lo ti gba ami ẹyẹ lorisirisi nidi awada sise lori ayelujara.
Wo adẹrinposonu ori ayelujara miran to se ohun ribiribi lọmọ ọdun mẹwa:
Bẹẹ ba gbagbe, adẹrinposonu miran lori ayelujara, Emmanuela, toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹwa, gbe ohun ribi ribi se.
Emmanuela lo kọ ile awodamiẹnu kan fawọn obi rẹ, eyi to kede sori ayelujara.
Emmanuella, to bẹrẹ awada sise lori ayelujara lọmọ ọdun marun, ti wa kede loju opo Instagram rẹ pe, oun ti ra ile awodamiẹnu kan fun iya oun.
O wa kede pe oun n fi ile mọriri ọpọ atilẹyin, adura ati iwuri ti iya oun n se fun oun ni.