Burkina Faso: Ọ̀gágun Damiba ní òun yóò dá ìjọba padà fún olóṣèlú bí nǹkan bá ti dára

Olori ologun to ṣẹṣẹ dìtẹ gbàjọba lorilẹ ede Burkina Faso, Ọgagun Paul-Henri Damiba ti ṣeleri lati da ijọba pada fun alagbada nigba ti akoko ba to.

Ọgagun Damiba lo ṣiwaju awọn ọmogun to gbajọba Aarẹ Roch Kaboré lọjọ Aje.

O di ẹbi ru Aarẹ Kaboré pe o kuna lati dẹkun iwa ipa ẹgbẹ musulumi alakatakiti.

Pẹlu fila pupa lori rẹ, Lt-Col Damiba ba awọn eeyan orilẹ ede Burkina Faso lori ẹrọ amohunmaworan ijọba fún igba akọkọ lati igba to ti gba to ti dìtẹ gbàjọba ni Ọjọbọ.

Ọgagun Damiba ni nigba to ba ya, oun yoo da ijọba pada fun ijọba alagbada, nigba ti ohun gbogbo ba pada bọ sipo.

Damiba to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji ṣalaye pe oun yoo ṣe ipade pọ pẹlu awọn lẹgbẹ lẹgbẹ ati lajọ lajọ ni Burkina Faso lati jiroro lori atunṣe ati ilọsiwaju orilẹ ede naa.

Ọgagun Damiba ni Burkina Faso nilo awọn alabaṣiṣẹpọ kaakiri agbaye lasiko yii.

Damiba ni "mo n fi asiko kepe awọn lajọ lajọ kaakiri agbaye lati dide iranwọ si Burkina Faso ki o le kuro ninu ìṣòro to n doju kọ ọ lasiko yii."

Ileeṣẹ ologun ni tori eto abo to mẹhẹ lorilede naa lo jẹ kí àwọn ditẹ gba ijọba.

Ọpọ eeyan lo koro oju sí Ààrẹ Kaboré lori ikuna ijọba rẹ lati dẹkun awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin musulumi.

Ipa ti ọgagun Damiba to ditẹ gbajọba ko lori ọrọ ẹgbẹ agbesunmọmi:

Ọgagun Damiba jẹ ọkan gbogii lara awọn to tako awọn agbesunmọmi lorilẹ ede Burkina Faso.

Koda, ọgagun Damiba kọ iwe jade lori ọrọ naa lọdun 2021.

Iṣẹlẹ iditẹgbajọba lẹkun iwọ oorun Afirika:

Iru iṣẹlẹ igbesunmọmi bayii naa lo jẹ kí àwon ologun ditẹ gbajọba loṣu karun un ọdun 2021 lorilẹ ede Mali.

Ohun to ọpọ lẹnu ni pe inu awọn araalu dun si b'awọn ologun ṣe gbàjọba ni Mali.

Burkina Faso ni orilẹ ede kẹta ní ẹkun iwọ oorun Afirika t'awọn ologun ti gbajọba laipẹ yii.

Ajọ ECOWAS ti fofin de orilẹede Guinea ati Mali lati da ijọba pada fun alagbada.

Amọ, awọn ologun ko tii da ijọba pada fun alagbada titi di asiko yii.

Ajọ ECOWAS yoo tun jiroro lọjọ Ẹti lori ọna ati wa ojutu sí iṣẹlẹ ijinigbe lẹkun iwọ oorun Afirika.