Kuburat Alaragbo Waka Queen: Tí èmi àti Salawa Abeni bá pàdé lórí "stage' lónìí, ẹrù ò ba odò tèmi o

"Baba mi ni Alhaji Ayinla Kolington jẹ́, ẹ̀gbọ́n mi ni onílù wọn tó máa ń jẹ́ ká gbaradì fún orin wa".

Alhaja Kuburat Alaragbo naa jẹ olorin Yoruba obinrin ti oun naa n kọ orin Waka yatọ si gbajugbaja ti awọn eeyan mọ iyẹn Queen Salawa Abeni.

gẹgẹ bi iwadi ati nkan ti oun funra rẹ sọ fun BBC Yoruba, Alaragbo gan ti n kọ orin lati ọjọ pipẹ bii ti Salawa Abeni ni ninu orin Waka bẹẹ si ni awọn to ba jẹ ololufẹ orin Waka gidi mọ ọ bi ẹni mọ owo tori oun naa di ilumọọka lasiko to n kọrin to si di olorukọ ṣugbọn o di asiko kan ti ko sẹni to rii mọ.

Ẹwẹ, Kuburat Alaragbo ninu ifọrọwanilẹwo BBC Yoruba sọ pe digbi ṣi ni orin Waka n bẹ lẹnu koda o ni orin pọ sile amọ ọlaju atawọn nkan mii lo n ṣe idiwọ fun ai le gbe orin tuntun jade.

Ni nkan bii 1980s, Kuburat Alaragbo gbayii gidi gan pẹlu awọn orin rẹ.

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Kuburat Alaragbo to ṣalaye idi ti wọn ko fi gburo rẹ mọ ati ohun to wa n ṣe bayii lati pada sori itage.