Husband kills wife in Ebonyi: Háà! Ọlọ́pàá fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ọkọ pé ó pa ìyàwò rẹ̀ tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ka oniṣowo

Ninu ifẹ ti ko yẹ ko ti tabi yẹ ni eleyi to wa laarin ọkọ ati iyawo.

Ṣugbọn ti ọkan ninu awọn mejeeji ba fi ẹtan bọ ọrọ ifẹ wọn, ohun to maa n kẹyin iru ibaṣepọ bayii kii suwọn.

Bẹẹ lọrọ ri laarin tọkọtaya kan ti ọlọpaa mu ọkọ pe o lẹdi apo pọ pẹlu awọn eeyan marun un kan lati pa iyawo rẹ.

Ni ipinlẹ Ebonyi ni iṣẹlẹ yi ti waye nibi ti awọn ikọ ọtẹlẹmuye ọlọpaa IRT si ti mu eeyan mẹrin kan to ji arabinrin Nneka Nwayi-Sunday Emeh Kalu gbe ti wọn si tun pa a.

Inu oko ẹgẹ ni wọn lawọn ti ri oku rẹ lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2021 ni abule Ngugworo Community to wa ni Nguzu Edda nijọba ibilẹ Afikpo South, Ebonyi.

Orukọ awọn afurasi ti wọn mu ni Irem Ifeanyi Mbah, Igwe Anya Chima, Okorie Okam ati Emeh Kalu to jẹ ọkọ arabinrin naa.

Emeka lawọn ọlọpaa pe ni ogunagbongbo to pa to si kun gbogbo ete lati ji arabinrin naa gbe.

Iwadii awọn ọlọpaa gẹgẹ bi wọn ti ṣe wi ninu atẹjade lati ọdọ alukoro ọlọpaa Frank Mba safihan bi ọkọ arabinrin naa ṣe pete pero nitori pe o fẹ j'ogun arabinrin naa.

A gbọ pe Nneka ni ọpọ ile, owo ati oko owo to n mu owo wọle fun daada.

Iwadii wọn sọ pe arakunrin naa lo tan iyawo rẹ lati lọ gba nkan wa ki awọn iyoku rẹ to jingbe.

Wọn ni lẹyin ti wọn fiya jẹ obinrin naa lati le sọ ibi to ko iwe ile ati dukia rẹ si, wọn yin lọrun ti wọn si lọ ju oku rẹ sinu igbo.

Awọn agbofinro sọ pe iwadii n tẹsiwaju lati le mu awọn to ku lara awọn to hu iwa aburu yi.