You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tinubu Presidency 2023: Mo ṣèlérí láti lọ gbà'mọ̀ràn gidi kí n tó ṣe ìpinu dídupò ààrẹ ní 2023
Adari ninu ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress (APC), Asiwaju Bola Ahmed Tininubu ti fesi lọ jọ Iṣẹgun lori gbigbe apoti idibo gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Tinunbu ni oun yoo rii daju pe o gba imọran kaakiri lọdọ eeyan pupọ o to ṣe ipinu boya yoo dije du ipo aarẹ ninu idibo to n bọ lọdun 2023.
Asiwaju sọ ọrọ yii jade lẹyin ipade atilẹkun m'ori ṣe to waye l'Abuja pẹlu awọn adari igbimọ apapọ to wa lati iha Ariwa.
"Mi o ni ta wọn nu," o sọ eyi nipa ti awọn to n pe fun ko di aarẹ. "But maa ṣi gba imọran to mọyan lori ati latọdọ ọpọlọpọ eniyan.
Paapaa julọ, maa jiroro pọ pẹlu awọn ọrẹ mi lati wa ọjọ kan ti n o jade wa si gbangba kede rẹ fun awọn ọmọ Naijiria".
Tinubu ni amọṣa, aarẹ ṣi wa lori ipo yii ou ko si fẹ ṣì í lọkan pẹlu gbogbo nkan to tun n koju lasiko yii. "Nitori naa, ẹ ma da omi oṣelu ru o. Ẹ gba imọran kẹẹ si jẹ ki awọn eeyan mọ nipa eto wa nigba to ba ya.
O ni ẹ o rii pe erongba oun ko farasin tori naa, "ẹ lee maa sọ eyi jẹ eyi o jẹ nipa rẹ".
Ipade to ṣe yii lọjọ Iṣẹgun jẹ eyi ti eeyan lee ri gẹgẹ bii ọkan lara ibere fun imọran ṣaaju erongba rẹ lori didu ipo aarẹ lọdun 2023.
Ṣaaju akoko yii, tẹ o ba gbagbe, awọn adari ati oloṣelu kan to fi mọ gomina Eko Babajide Sanwo-Olu ti jan an lontẹ ni gbangba pe ki Tinubu maa lọ fun aarẹ, awọn wa lẹyin rẹ. Wọn pe akanṣe eto atilẹyin yii fun Tinubu ni SWAGA.