Katsina Kidnap: Ọmọ lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ará abúlé méjì láti jí bàbá rẹ̀ gbé gba owó

Hamza Isah, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn to wa lati abule Rinjin Gora nipinlẹ Katsina ti jẹwọ pe oun lo lẹdi apo pọ mọ awọn ajinigbe lati gbe baba rẹ ninu ile wọn.

Hamza ni ẹgbẹrun lọna igba naira ni awọn agbebọn naa seleri lati fun oun lori isẹ naa.

Ọdọkunrin naa, ti oun ati baba rẹ, Alhaji Isah Maigora tii se ẹni ọgọta ọdun maa n saba woju ara wọn, lo n sọ tẹnu rẹ ni agọ ọlọpaa bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Hamza ni oun ati eeyan meji miran, ni abule awọn, ti gbogbo wọn dijọ wa ni ahamọ ọlọpaa, ni awọn dijọ pete pero lati gbe baba oun, ẹni to si wa nibi ti wọn fi pamọ si, ti ẹnikẹni ko tii mọ bayii.

Osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Isah Gambo, lo fi oju awọn afurasi ajinigbe naa han fawọn akọroyin ni olu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lọjọ Ẹti.

"Mo maa n ba baba mi ja ni ọpọ igba ni. Mo wa lọ si ọdọ Auwal Magaji pe ko ran mi lọwọ pẹlu ajilẹ.

Amọ o ni kii se nipa ajilẹ nikan ni oun uoo fi ran mi lọwọ, amọ oun yoo fun mi ni owo to pọ, ti mo ba gba lati se iranwọ fun wọn lati ji baba mi gbe.

Loju ẹsẹ naa lo ti fun mi ni ẹgbẹrun lọna ogun naira, to si seleri pe oun yoo fun mi ni ẹgbẹrun lọna igba naira, ti wọn ba ji baba mi gbe, ti wọn si ri owo gba lọwọ rẹ.

Mo ni yoo nira pupọ lati ri baba mi gbe nitori aabo to daju wa ni ayika wa amọ wọn ni ki n ma yọ ara mi lẹnu nipa iyẹn.

Wọn wa fun mi ni orisi oogun abẹnu gọngọ mẹfa pe ki n ri mọlẹ ni agbala wa, mo si se bẹẹ;

Lẹyin ọjọ kẹta ni wọn wa sinu ile wa, ti wọn si ji baba mi gbe lọ, amọ mo pinnu lati tu asiri ọrọ yii.

Idi ni pe lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ji baba mi gbe, mo lọ ba Auwalu Magaji pe mo fẹ da owo to fun mi pada, amọ o ni ẹmi mi wa ninu ewu ti mo ba sọ fun ẹnikẹni.

Amọ nigba ti awọn ọlọpaa gbe mi wa si ahamọ wọn, ti iya nla si jẹ mi ni mo ba tu asọ loju eegun, ti mo si tu asiri naa sita."

Amọ agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa sọ fawọn akọroyin pe ẹgbọn Hamza, ti orukọ rẹ n jẹ Buhari Isah, lo n fura nipa awọn ọrọ to n jade lẹnu aburo rẹ lẹyin ti wọn ji baba wọn gbe tan.

O ni se ni aburo oun n leri leka pe oun yoo ni owo to pọ laipẹ laijinna.

Idi ree ti Buhari fi ke sawọn ọlọpaa pe ki wọn wa da si ọrọ naa, lasiko ifọrọwanilẹnuwo naa si ni asiri tu.

Amọ awọn afurasi meji yoku ti wọn fi ẹsun ijinigbe naa lan ti sẹ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ yii, ti ileesẹ ọlọpaa si ni iwadii si n lọ lọwọ nipa isẹlẹ naa.