INEC preparations for 2023 general poll: Ó ṣeéṣe kí àwọn òkú lẹ́tọ́ láti dìbò lọ́dún 2023, ìdí rèé gẹ́gẹ́ bí àjọ INEC ṣe sọ

O ṣeeṣe ki o ri orukọ awọn eeyan ti o mọ ti wọn ti ku ninu iwe orukọ awọn oludibo Naijiria o.

Maṣe pariwo kinla rara!

Alaga ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ti ṣalaye ohun to lee ba eyi wa o.

Ọjọgbọn Mamood Yakubu ṣalaye pe ohun to ṣokunfa eyi ko ju wi pe ajọ INEC ko lanfani ati ṣe akọsilẹ to pe nipa awọn to ti ku lorilẹede Naijiria. Eyi, gẹgẹ bi ọrọ rẹ, lo n pagidina bi ajọ naa ṣe lee yọ orukọ wọn kuro ninu iwe.

Nigba to n gba Nasir Kwara to jẹ alaga ajọ ikaniyan lorilẹede Naijiria, NPC lale lolu ileeṣẹ ajọ INEC ni Ọjọgbọn Yakubu sọ ọrọ yii.alaga ajọ INEC naa ni awọn n gbiyanju loorekoore latiu maa yọ orukọ awọn ti ko lẹtọ lati dibo ni Naijiria nipasẹ imọ ẹrọ ṣugbọn imọ ẹrọ ko lee ran ajọ naa lọwọ lati mọ awọn to ti jade laye ninu iwe idibo.

O wa rọ ajọ ikaniyan ni Naijiria lati maa ṣeranwọ fun ajọ INEC paapaajulọ nipa orukọ awọn oṣiṣẹ ijọba to ti ku gẹgẹ bi wọn ba ṣe koo jọ pọ latinu awọn iwe akọsilẹ awọn ileeṣẹ ijọba ati ajọ ijsba gbogbo lati awọn ileewosan kaakiri Naijiria.