Lagos cemetery: Ìjì tó hú igi ńlá ní ìtẹ́ òkú l'Eko ba ibojì òkú 50 jẹ́, àwọn ẹbí sáré dìgbà dìgbà

Iji lile ti wo igi nla to wa ni ilẹ isinku agbegbe Abari, ni ijọba ibilẹ lla orun ipinlẹ Eko.

Iṣẹlẹ yii da omi alaafia agbegbe naa ru, eyi to mu ki awọn mọlẹbi sa kijo-kijo lọ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni o kere tan, aadọta iboji oku ni igi nla to wo lulẹ lasiko iji lile naa bajẹ.

Igi to wo lule naa ni awọn aṣọgba ni o ti le ni ẹgbẹrun ọdun ti igi naa ti wa ninu itẹ naa ki o to wolulẹ.

Iroyin lẹnu awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe aago mẹsan alẹ lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ibẹ ti dari lọ si ile ni iṣẹlẹ naa waye, to si ba awọn iboji miran jẹ patapata, nigba ti awọn miran ko fi bẹẹ faragba igi to wo lulẹ naa.

Lara awọn oṣiṣẹ ibẹ sọ pe igba keji re e ti igi nla yoo wo lulẹ ni agbegbe naa, ti wọn si ge igi naa si wẹwẹ.

''O ṣeni laanu pe wọn ko le e tun awọn iboji naa ṣe lasiko yii, nitori wọn kọkọ gbọdọ gbe igi naa kuro ni bi to wo lulẹ si''

''Bakan naa ni alaga ijọba ibilẹ naa ti kesi awọn ti yoo ge igi naa, ki awọn mọlẹbi le tun iboji oku wọn ṣe''

Ni kia ti iṣẹlẹ naa waye ni awọn mọlẹbi ti wọn sin eniyan wọn si bẹ ti n salọ si iboji naa lati wo ipa to ni lara ẹni wọn to sun si ibẹ.

Alaga ijọba ibilẹ naa tun fi atẹjade ranṣẹ si awọn mọlẹbi ti wọn sin oku si ibẹ lati wa wo boya igi to wo lulẹ naa ni ipa abi ko ni ipa lori awọn eniyan wọn to sun si ibẹ.