You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Police shooting in Osogbo: Ọlọ́pàá MOPOL yìnbọn fún Ọlabomi, ọlọ́kadà nílùú Osogbo
Wahala iwọde ti bẹ silẹ ni ilu Oṣogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.
Ohun ti awọn iroyin abẹle ṣalaye pe o fa eyi ni bi wọn ṣe ni awọn ọlọpaa kan yinbọn pa smọdekunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Saheed Ọlabomi ni agbegbe Oke Onitea nilu Oṣogbo.
Iṣẹlẹ naa la gbọ wi pe o ṣẹlẹ ni nnkan bii agogo marun un ọjọ Iṣẹgun ti wọn si ti gbe ọmọkunrin naa lọ si ileewosan nla LAUTECHTH nilu Oṣogbo kan naa.
- Wo ìdí tí báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà CBN fi tilẹ̀kùn mọ́ àwọn aṣẹ́wó dọ́là, pọ́ùn ní Nàìjíríà
- Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha di oṣu kẹ́jọ lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọmọ́débìnrin tọ́rọ̀ kàn lẹ́nuwò
- Ẹ gbé Sunday Igboho kúrò láhàmọ́ ọlọ́pàá wá sí ibi ìpamọ́ mìí ní Cotonou títí tí... - Adájọ́
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe iṣẹ alupupu gigun ti ọpọ mọ si ọkada ni Ọlabomi n ṣe.
Wọn ni awọn ọlọpaa atawọn awakọ akoyanrin ni wọn n fa wahala ki awọn ọlọpaa to bẹrẹ si nii yinbọn soke lakọlakọ.
Aṣita ibọn ti wọn n yin lakọlakọ naa lo lọ ba Ọlabomi nibi ọrun lori ọkada rẹ.
Ni asiko ti a n ko iroyin yii jọ, gbogbo oju popo lagbegbe naa lawọn ọlọkada atawọn ọdọ ti n fi ẹhonu han ti wọn si n jo taya ọkọ kaakiri awọn agbegbe bii Okefia nilu Osogbo.