Ugieki Asemota: Wọ́n fẹ̀sùn kan Emmanuel pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa nílùú Benin nítórí ó kọ ìbálòpọ̀

Ọmọbinrin kan niluu Benin nipinlẹ Edo, Ugieki Asemota, ti dero ọrun ọsan gangan, lẹyin ti ọkọ rẹ, Emmanuel lu u pa nitori ko gba ki o ba ni ibalopọ.

Iwe iroyin Punch jabọ pe ede-ai-yede ṣẹlẹ Emmanuel ati Ugieski lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa to lọ nile wọn to wa ni opopona Abaegbe lagbegbe Evbotubu niluu Benin.

Ohun ti a gbọ ni pe Ugieki wọ yara rẹ lọjọ ti a n wi yii, o si ti ilẹkun mọri ko maa ba si ija laarin oun ati ọkọ rẹ.

Ṣugbọn iroyin sọ pe Emmanuel ni o gbọdọ ṣi ilẹkun, nigba to kọ ti ko ṣi ilẹkun lo bẹrẹ si ni lo aakee lati fi ja ilẹkun mọ lori.

A gbọ pe Ugieki gbiyanju lati gba oju ferese jade nigba to ri pe ọkọ rẹ ti fẹ ja ilẹkun mọ ọn lori.

Amọ, nibi ti o ti n gbiyanju lati gba oju ferese sa lọ ni Emmanuel ti lọ ka a mọ bẹ ti o si bẹrẹ si ni lu u ni alubami titi ti o fi daku.

Victoria Omoruyi to jẹ arabinrin Ugieki ṣalaye pe ile iwosan meji ni ko gba Ugieki nigba ti wọn n gbe e kiri.

Omoruyi ni igbeyawo Ugieki ati Emmanuel kun fun ija ni gbogbo igba ati iwa ipa.

O ṣalaye siwaju sii pe Emmanuel ati Ugieki ti n ja tẹlẹ ṣaaju ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni ni gbogbo igba ni ọkọ rẹ maa n lu u ni aluki.

''Ṣugbọn lalẹ ọjọ ti a n wi yii, Emmanuel fẹ ba a ni ibalopọ, amọ Ugieki ni ko maa lọ si yara rẹ jẹjẹ nitori oun ko fẹ wahala.

Amọ ni bi ago mejila oru ni Emmanuel bẹrẹ si ni kan ilẹkun mọ ọn lori ki o to bẹrẹ si ni lo aakee lati jẹ ilẹkun.

Ugieki bẹ Emmanuel nigba ti o n lu pe ẹmi oun ti fẹ bọ, ṣugbọn ko gbó, afigba to lu u debi pe ko le sọrọ mọ.

O gba itọju nile iwosan fun ọjọ dẹ ki o to jẹ Ọlọrun nipe,'' Omoruyi lo ṣalaye bẹẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Kontongs Bello to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣo pe Emmanuel yoo foju ba ileẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori iṣẹlẹ ọhun.