June 12 Democracy Day: Ọ́pọ́ ọmọ Nàíjíríà tó ń ṣèwọ́de ní kí aráàlù ra oúnjẹ sílé

Gbogbo ilu lo ti n rọ kẹkẹ bayii fun eto isami ayajọ ọjọ isejọba alagbada kẹrin to bẹrẹ lọdun 1999 lorilẹede Naijiria.

Ayajọ ijọba alagbada yii, ni aarẹ Buhari kede lọdun to kọja pe yoo maa waye bayii lọjọ Kejila osu Kẹfa dipo ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Karun ọdọọdun to maa n waye tẹlẹ.

Pataki ọjọ Kejila osu Kẹfa naa, taa mọ si June 12 si ni lati bu ọla fun oludije fun ipo aarẹ nigba naa, Oloye MKO Abiola, to jawe olubori ninu ibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibo yii si ni gbogbo agbaye lo jẹ itẹwọgba julọ ninu itan eto idibo lorilẹede Naijiria.

Nibayii ariwo ti n rọ kẹkẹ laarin ilu nipa ayajọ June 12 yii, eyi to ko lọjọ Satide ọla, ti omimi si ti n milẹ pẹlu nipa ayajọ naa.

Idi ni pe oniruuru awọn eeyan to setan lati sami ayajọ naa lo n kede bi sla Satide yoo se ri lorilẹede Naijiria.

Bi awọn ọdọ, ẹgbẹ akẹkọọ, ajafẹtọ ẹni, oloselu, awọn eeyan to n jijagbara fun iyapa Naijiria se n kede eto ti wọn ni, naa ni ijọba n sọ tiẹ.

Ọna tawọn Ajafẹtọ ẹni, ẹgbẹ Akẹkọọ ati Ajijagbara fẹ gba sami ayajọ June 12.

Ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni atawọn ẹgbẹ ọdọ to jẹ akẹkọọ lo ti n figbe bọnu nigboro pe ọjọ Satide ọla yoo ro lasiko ayajọ June 12 yii.

Wọn ni ọjọ naa ni awọn yoo fi se iwọde lati tako ipo ti ko dara ti orilẹede Naijiria wa.

Yoruba Nation ni iwọde alaafia n bọ ni June 12:

Awọn ikọ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti kede pe gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Kaarọ Oojiire bii Eko, Oyo, Ogun, Kwara, Ondo, Osun ati Ekiti, ni iwọde yoo ti waye lọjọ Kejila osu Kẹfa.

Ikọ naa wa n rọ awọn gomina to wa nilẹ Yoruba lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ki alaafia le jọba lasiko iwọde naa.

Ikọ naa tun rọ awọn araalu lati ra ounjẹ pamọ sile wọn, ti wọn si ni bi iwọde naa ba se n waye ni Naijiria, naa ni yoo maa waye nilu Oyinbo lorisirisi.

Awọn asaaju ninu ikọ to n pe fun Yoruba Nation, to fi mọ Oloye Sunday Igboho ti wa n ke si gbogbo awọn ajijagbara lati kopa ninu iwọde naa, eyi ti wọn yoo lagbara.

Ẹgbẹ Akẹkọọ Naijiria ni ko si yatayoto kankan, iwọde nla lawọn yoo fi sami June 12:

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede yii, NANS si ti fi ikede sita pe June 12 yii ni awọn yoo se iwọde alagbara lati tako eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Aarẹ ẹgbẹ NANS lapapọ, Comrade Sunday Asefon ni ko si ohunkohun to wu awọn akẹkọọ lori, ti yoo fi maa fi ayọ sami ayajọ June 12, nigba to jẹ pe ọpọ awọn ọdọ rẹ ni awọn agbebọn ti da ẹmi wsn legbodo.

Asefon, lasiko ipade akọroyin to se wa n ke sawọn akẹkọọ nilẹ Naijiria lati jade sita ni ọjọ June 12 wa se iwọde nitori n ko le wa ku, kii joye ile baba rẹ.

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọẹni yari pe iwọde alagbara n bọ ni June 12:

Ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajijagbara naa ti kede pe awọn ti gbara di fun iwọde nla ti yoo waye ni June 12.

Lara awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni naa ni Arise Nigeria ati Revolution Now.

Ẹgbẹ arise Naijiria yii, ti ọpọ wọn jẹ ọdọ si ni ariwo wsn gbode kan lori ayelujara pe June 12 yoo gbona fun iwọde kan tawsn n palẹ rẹ mọ.

Wọn ni O to gẹẹ, awọn ko le dakẹ ku ki ohun gbogbo ni Naijiria si maa bajẹ lasiko awọn, ti wọn si n ke si ijọba lati mura silẹ, nitori awọn n bọ nigboro.

Bakan naa ni ẹgbẹ Revolution Now ti Omoyele Soworẹ ko sodi ti wa n lọgun fun awọn araalu lati ra ounjẹ sile nitori ohun gbogbo yoo pakasọ.

O ni iwọde nla n bọ ni Satide June 12, ti awọn yoo si ti gbogbo ọja, ibudokọ, sọọsi, mọsalasi, ati ile ẹkọ pa ni gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria.

Soworẹ ninu ikede kan to fi sita loju opo Facebook rẹ ni iwọde yii nikan ni ọna lati jẹ ki ijọba aarẹ Buhari mọ pe o ti kuna.

Ẹ sami ayajọ June 12 lọna alaafia - Ọga agba Ọlọpaa Naijiria

Ọga ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba ti rọ awọn araalu lati ṣe ayajọ ijọba awarawa pẹlu alaafia lai da rogbodiyan kankan silẹ.

Ọga ọlọpaa Baba sọrọ yii lasiko abẹwo ọlọjọ mẹta to ṣe si ipinlẹ Eko lọjọru.

Ọga ọlọpaa wa rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn yọ ayọ mọ ni wọn, ki onikaluku si maa ṣiṣẹ rẹ lai pa ẹlomiran lara.