You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bola Tinubu: Kókó ọ̀rọ̀ mẹ́wàá tí Asiwaju sọ rèé lórí aáwọ̀ darandaran àti agbẹ̀
Yoruba ni aisi nibẹ, ni aibawọn da si, agba kii si wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ.
Eyi lo mu ki asaaju ẹgbẹ oselu APC nilẹ yii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fi sọrọ soke lori aawọ to n waye yika Naijiria nipa ọsẹ tawọn ọdaran darandaran n se.
Ninu atẹjade kan to fisita lọjọ abamẹta, Tinubu ni aawọ yii ti n gbọna ọtun yọ, to si gbe imọran kalẹ pe ki wọn sọ awọn ilẹ ilu ti wọn ko lo di ibudo ọsin ẹran.
- EFCC ń wádìí iléeṣẹ́ 'Bola Tinubu,' Alpha Beta Consulting Ltd'
- Fulani nìkan kọ́ ló ń pa ènìyàn ní Naijiria -Tinubu
- Ìṣòro jíjẹ́ ìyá n dáàgbé ló sọ mí di àtúnbí krístíẹ́nì - Remi Tinubu
- Tinubu, yé é sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀, bọ́ sí gbangba láti bèèrè àtúntò Nàíjíríà lọ́dọ̀ Buhari - Afẹnifẹrẹ
- Tinubu kò ṣékú, kò ṣé ẹyẹ, o n dibọn ní lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Amotekun - Fani Kayode
- Ooni Ile ife ṣàlàyé ohun tí Tinubu níló fún ilépa ipò ààrẹ lọ́dún 2023
O ni a le mọ odi yika awọn ilẹ ti a ko lo bayii lati haaya rẹ fawọn darandaran fun sinsin ẹran ni owo ti ko gunpa, eyiun awọn to ba fi orukọ silẹ.
Tinubu ni "Imọran oun yoo jẹ kawọn darandaran le joko sisẹ wọn pẹlu pipa ere nla wọle ti wọn ba fi ilẹ ti a ko lo haaya fun wọn lowo pọọku.
Amọ eyi ko wa lati fiya jẹ awọn darandaran amọ owo iforukọsilẹ ti wọn ba san yoo jẹ kawọn naa ni owo idokowo lori isẹ naa ni, eyi yoo si fopin si ariyanjiyan to n waye lori fifun awọn darandaran ni ilẹ
Lara awọn koko ọrọ ti Tinubu tun sọ ree:
- Agbekalẹ igbimọ laelae kan fun ijiroro laarin awọn agbẹ, darandaran, agbofinro atawọn asoju ijọba nipinlẹ kọọkan, eyi ti yoo jẹ ki wọn tete mọ ti aawọ ba wa, lati bomi pana rẹ
- Aawọ darandaran ati agbẹ ti mu ọpọ ẹmi ati dukia lọ pẹlu afikun pe oju ọjọ ti ko dara ati ọrọ aje to n saisan gan da kun aawọ naa
- O ni ki ijọba se amulo imọ ẹrọ igbalode ati ohun eelo fun nini iroyin larọwọto ati itọpinpin ohun to n lọ yika ilu lọna ati ro awọn agbofinro lagbara si
- Tinubu ni ki awọn ijọba ipinlẹ kọọkan naa se agbekalẹ ipade igbimọ eleto aabo eyi to kan awọn alẹnulọrọ ninu aawọn to n waye yii, gẹgẹ bi ijọba apapọ ti se
- Aawọ darandaran ati agbẹ kii se ija ẹlẹyamẹya, ko si yẹ kawọn araalu maa sọrọ kobakungbe lati bu epo bẹtiroolu sọrọ naa
- Ilana dida ẹran jẹko ni ita gbangba ti di asa atijọ, ti ko jẹ itẹwọgba mọ, eyi to n tako ilan ibagbepọ alaafia laye ode oni
- Ki ijọba ipinlẹ kọọkan pese omi ati ounjẹ ẹran lowo ti ko gunpa fawọn darandaran lawọn ibudo ti wọn ba wa eyi ti yoo jẹ ko rọrun fun wọn lati se ọsin ẹran wọn
- Awọn darandarn yoo di onisowo awọn eroja miran, yatọ si ọsin ẹran. Awọn eroja ti wọn ba n fi awọ maalu se ni wọn le maa fi sọwọ sawọn onileesẹ to nilo wọn
- Bakan naa ni awọn darandaran atawọn agbẹ yoo di ọrẹ imulẹ, nigba tawọn darandaran ba n fun awọn agbẹ ni igbẹ maalu, eyi ti yoo jẹ ki oko wọn tubọ ni ọra, tawọn agbẹ naa yoo si maa fun awọn darandaran ni koriko tawọn maalu yoo maa jẹ.