You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Orisabunmi: Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN, Baba Latin sọ̀rọ̀ lórí ìgbà tí ìsìnkú Orisabunmi yóò wáyé
Nigba wo ni wọn yoo sin gbajumọ eekan oṣere tiata ati sinima Yoruba ni, Oriṣabunmi?
Eyi gan an ni ibeere to n jade lẹnu ọpọ awọn ololufẹ oloogbe naa ti wọn fẹ bu ọla ikẹyin fun.
Ọpọ awọn ololufẹ ere tiata ati sinima Yoruba lo ji si iyalẹnu ati ibanujẹ ọkan l'Ọjọru nigba ti iroyin iku oloogbe naa jade si igboro.
Iroyin sọ pe ni ọjọ Iṣẹgun ni arabinrin Fọlakẹ Arẹmu ti ọpọ mọ si Oriṣabunmi jade laye.
Gẹgẹ bi iwe ibanikẹdun kan ti awọn iwe iroyin abẹle ṣalaye pe aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba ti a mọ si TAMPAN, Bọlaji Amuṣa ti ọpọ mọ si Baba Latin fi ọwọ si, ko tii si ẹni mọ igba ti wọn yoo sin oku Oriṣabinrin.
"Ikede eto isinku rẹ yoo waye laipẹ"
Baba Latin ni aloyinlohun ni Oriṣabunmi to gbo lede pẹlu ohun to dun leti.
Ọmọ bibi Ilu Olla ni ipinlẹ Kwara si ni Oriṣabunmi jẹ.