Oby Ezekwesili: Mínísítà tẹ́lẹ̀ ní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà báyìí fihàn pé Ààrẹ Buhari nílò àyẹ̀wò ọpọlọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹ ba wa ṣayẹwo ọpọlọ ati ilera ara aarẹ wa o?

Eyi ni igbe ti Oby Ezekwesili, minisita tẹlẹ lorilẹede Naijiria kesita loju opo twitter rẹ latari bi nnkan ṣe nlọ si lorilẹede Naijiria bayii.

Oby Ezekwesili ni ẹtọ ọmọ Naijiria ni bayii lati mọ bi ilera ẹni to n tukọ iṣẹjọba orilẹede wọn ṣe jafafa si atipe dokita agba ileewosan ile ijọba Aso rock ko ni lee ṣe irufẹ ayẹwo bẹẹ.

Minisista tẹlẹ naa ni ayafi ki wọn ṣe agbekalẹ igbimọ oluwadii iṣegun kan lati ṣe ayẹwo naa.

"Ero mi ni pe ni ipele ti a de bayi lorilẹede Naijiria pẹlu bi ọkọ orilẹede yii ṣe n fi logbologbo, o yẹ ka fi ọrọ ẹtọ si ẹgbẹ kan lori ilera aarẹ Buhari.

A nilo lati ṣe ayẹwo ijipepe ilera ara ati ọpọlọ aarẹ orilẹede Naijiria lati mojuto ojuṣe ipo to di mu".

O ni bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayii fihan pe asiko yii kii ṣe asiko fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati joko kawọgbera tabi fi ọwọ leran.

O fi kun pe, "Gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria tọrọ n dun, mo pe fun igbekalẹ igbimọ oluwadii iṣegun kan lati ṣe ayẹwo naa nitori a ko le gbara le dokita ileewosan ile ijọba mọ lati fun wa ni iroyin to ṣee fọkan tan".

Ipe ajafẹtọ ọmọniyan to tun figbakanri jẹ minisita feto ẹkọ lorilẹede Naijiria naa ko lee ṣai da lori bi ọrọ eto abo lorilẹede Naijiria ti ṣe n di awo-dọwọboju bayii, paapaajulọ pẹlu ti awọn agbẹ onirẹsi to le ni ọgọrun tawọn agbebọn Boko Haram pa lopin ọsẹ to kọja.