Lagos State Task Force: Lóòótọ́, a tí mú Ọlọ́páà to f'ọ̀nà ẹ̀bùrú gba owó ẹ̀yìn N100k lọ́wọ́ awakọ̀

Ọwọ palaba ọga ọlọpaa kan ti ṣegi lẹyin to gba owo abẹtẹlẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira lọwọ awakọ to tapa sofin oju popo nilu Eko.

Alukoro igbimọ amuṣẹya lori ọrọ ayika Adebayo Taofik lo sọ fun BBC Yoruba pe ọga ọlọpaa yi wọ gau lẹyin ti o gba owo lọwọ awakọ naa to rufin lagbegbe Lekki Ajah.

Popoola Kayode lo pe orukọ ọga yi to si ni ọkan lara awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya lori gbigbogun ti iwa to lodi si ofin irina nii ṣe.

Adebayo ni lẹyin toun ati awọn ọmọ iṣẹ rẹ mu awakọ obinrin kan Didi Ekanem to n gba One Way lọjọ Kejidinlogun oṣu Kọkanla, wọn gbe ọkọ rẹ lọ si Alausa ni ibamu pẹlu ofin.

O ni Kayode gbẹyin awọn ọmọ ṣẹ rẹ lati sọ fun Obinrin naa ko san owo ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ki o ba le fi ọrọ naa ṣe oku ọrun.

Ṣugbọn asiri awo yi pada tu si ọwọ awọn igbimọ amuṣẹya lọwọ lẹyin ti iwe iroyin kan gbe ọrọ bi Kayode ṣe ni ki Ekanem san owo si akoto ifowopamọ si rẹ.

Alukoro Taofik Adebayo ṣalaye siwaju pe ọga igbimọ amuṣẹya yi Olayinka Egbeyemi sọ pe lootọ ni iroyin to gbode pe ọlọpaa ọmọ igbimọ naa lo gba owo abẹtẹlẹ.

O ni kia lawọn ti ṣe iwadii tawọn si ba owo naa lakoto rẹ.

Adebayo sọ pe ọga awọn paṣẹ lẹyin ti asiri ti tu ki awọn mu Kayode lọ si ileeṣẹ ọlọpaa fun ijiya to tọ si.

''A rọ araalu lati yago fun fifi owo abẹtẹlẹ lọ awọn agbofinro wa.,Mo fẹ fi da yin loju pe ati ẹni gbe epo laja ati ẹni gbaa, awọn mejeeji ni yoo foju wina ofin.Ile ẹjọ nikan lo le sọ iye tẹni ba tapa si ofin irina yoo san, akoto ijọba si ni owo yi yoo lọ''

Bẹẹ naa lo sọ pe ki awọn ara ilu ma ṣe jafara lati fẹjọ eyikeyi ọlọpaa to ba beere owo abẹtẹ sun ni kiakia.

Traffic violation One Way: A ti ṣetán látu lu ọkọ̀ 44 tí a gbẹ́sẹ̀lé ní gbàǹjo - Ìjọba ìpínlẹ Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn yoo ta ọkọ mẹrinlelogoji ti wọn gbẹsẹle lọwọ awọn eeyan to tapa s'ofin to rọ mọ irinajo oju popo ni ipinlẹ naa.

Agbẹnusọ gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile lo kede bẹ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter rẹ.

O ni "Igbimọ amuṣẹya lori ọrọ ayika ni ipinlẹ Eko fẹ fi akoko yii sọ fun awọn eeyan ilu pe, lẹyin ti a gba aṣẹ lọwọ ile ẹjọ gẹgẹ bi ilana ofin, a o lu awọn ọkọ ti a gbẹsẹle lọwọ awọn to tapa s'ofin ni gbanjo."

O sọ pe eyi yoo si waye ni gbagede ileeṣẹ ajọ wọn wa to wa lẹyin ile itaja Shoprite, ni Ikeja.

O tẹsiwaju pe wọn gbẹsẹle awọn ọkọ naa lẹyin ti aẉon awakọ wọn tapa s'ofin irinna oju popo ti ipinlẹ Eko gbe kalẹ lọdun 2018.

Bakan naa lo tun fi orukọ ati nọmba idanimọ awọn ọkọ ti wọn fẹ lu ni gbanjo naa lede pẹlu.

Ṣaaju ni ijọba ipinle Eko ti kọkọ kede pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o tapa s'ofin naa yoo ki ọkọ rẹ ni odigboṣe.

Lẹyin naa lo bẹrẹ si n lọgun, to si n kilọ fun awọn eeyan pe ki wọn ṣọra fun titapa si ofin irinna oju popo.Ṣugbọn ọpọ awakọ lo kọ eti ọgbọin si ikilọ naa, eyii to ṣalekun sunkẹrẹ-fakere oju popo ipinlẹ ọhun.