Ondo state Amotekun: Léyìn tí ìwọ́de EndSARS parí tán ni ìwà ọ̀daràn búrẹ́kẹ ní Naijiria

Adari ikọ Amotekun ni ipinlẹ Ondo, Adeleye Olusanyero, ti sọ fun BBC pe lati igba ti awọn janduku ti ja iwọde EndSARS gba mọ awọn oluwọde lọwọ ni eto abo ti mẹhẹ ni ipinlẹ Ondo.

Olusanyero lo sọ bẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.

Adari Amotekun naa ni yatọ si ohun to ṣẹlẹ lẹyin iwọde EndSARS, iwa ọdaran naa ti n peleke sii lasiko ti ọdun ba ti n sunmọ etile.

O ṣalaye pe ikọ Amotekun ni ipinlẹ Ondo n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe iwa ọdaran di ohun igbagbe ni ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "ninu awọn ti wọn ji gbe ni ilu Owo, laarin wakati mẹrin si akoko ti wọn ji wọn gbe ni a gba eeyan marun un mu pada."

"Bi a ṣe n sọrọ lọwọ yii, awọn afurasi meje to ji eeyan gbe ni agbegbe ilu Owo ni a ti fi panpẹ ofin mu ti a si ti fa le ọlọpaa lọwọ."

Olusanyero sọ fun BBC pe ojojumọ ni ikọ Amotekun maa n kaakiri ni ipinlẹ Ondo lati aago mẹjọ alẹ si marun un aarọ.

O ni "bi mo ṣe n ba yin sọrọ lọwọ yii, eeyan mẹrinla ni a ti da sinu igbo lati maa wa awọn iya ati ọmọ ti wọn ji gbe laipẹ yii."

Nigba to n da si ọrọ naa, onimọ nipa eto abo kan, Tunde Akande, ni ti ọdun ba ti n sumọle ni iwa ọdaran bii ijinigbe ati idigunjale maa n pọ si ni Naijiria.

Akande ni o yẹ ki awọn eeyan maa ṣọra wọn lasiko yii nitori oju ni alakan fi n ṣọri.

O ni aarin awọn ara ilu ni awọn ọdaran n gbe, nitori na lo fi yẹ ki awọn eeyan maa ṣe amí fun awọn oṣiṣẹ eto abo nitori wọn ko lee da iṣẹ naa ṣẹ.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro sọ fun BBC pe alaafia ni ipinlẹ Ondo wa nitori awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.

Ikoro ni awọn ọlọpaa ti gba awọn ti wọn ji gbe pada, ọwọ si ti tẹ awọn ọdaran to n ji eeyan gbe, nitori naa ko sewu loko.