You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EndSARS Protest: Ojú àwọn ọmọ Nàìjíríà tí yóò farahàn níwájú adájọ́ rèé
Ile ẹjọ Majisireeti kan niluu Abuja ti ke si Kọmisọna ọlọpaa to wa ni olu ilu naa lati ṣewadii eeyan aadọta ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣe onigbọwọ iwọde ifẹhonuhan EndSARS.
Eyi jẹ jade ninu lẹta ti adajọ Majisireeti, Omolola Akindele kọ ranṣẹ si kọmisọna ọlọpaa lẹyin iwe ipẹjọ ti ajafẹtọ ọmọniyan kan Ọgbẹni Kenechukwu Okeke kọ.
Lara awọn ti olupẹjọ naa ko orukọ wọn jọ niyii:
Pasitọ agba ijọ Daystar Christian Centre, Sam Adeyemi
Okeke to ni lasiko iwọde naa, wọn ba ọpọlọpọ dukia oun jẹ nitorina gbogbo awọn to ṣagbatẹru rẹ gbudọ foju fina ofin.
Maryam Apaokagi (Taaooma)
Awọn mii ti wọn pe lẹjọ ni awọn olorin bii Peter ati Paul Okoye, Innocent Idibia (Tuface), Bankole Wellington (Banky W), Tiwa Savage, Michael Ajereh (Don Jazzy), Ayo Balogun (Wizkid), ati Yemi Alade.
Folarin Falana (Falz)
Awọn ajafẹtọmọniyan to wa lara wọn ni Aisha Yesufu; Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles tẹlẹri, Kanu Nwankwo; oludari agba ileeṣẹ to n ri si atunṣe ilu tẹlẹri, Ọmọwe Joe Abah.
Aisha Yesufu
Debo Adebayo (Mr Macaroni)
Akọroyin, Kiki Mordi, to fi mọ awọn oṣere Yul Edochie and Uche Jombo naa wa lori iwe ipẹjọ naa.
David Adeleke (Davido)
Bakan naa, awọn ajafẹtọ ori ayelujara bii Feyikemi Abudu, Olorunrinu Oduala, Pamilerin Adegoke, Japhet Omojuwa, Ayo Sogunro, ati Deji Adeyanju, ati Tope Akinyode.
Damini Ogulu (Burna Boy)
Ninu lẹta rẹ, adajọ Akindele fun awọn ọlọpaa ni ọsẹ meji lati ṣewadii ọrọ naa ki wọn si da esi pada fun ileẹjọ.
Irọ́ ńlá ni pé àwọn sọ́jà ń wá olùwọ́de EndSARS DJ Switch- Ọ̀gágun Ahmed Taiwo
Ọgagun Brig. Gen. Ahmed Taiwo to ṣoju ileeṣẹ ologun oriilẹ niwaju igbimọ to n ṣe iwadii lori ifẹhonuhan EndSARS nipinlẹ Eko ti sọ pe irọ nla ni pe ileeṣẹ ologun n wa ọkan lara awọn oluwọde EndSARS Obianuju Catherine Udeh ti ọpọ mọ si DJ Switch.
Ọgagun Taiwo fidi ọrọ yii mulẹ niwaju igbimọ ọhun to n ṣe itọpinpin ibọn yinyin si awọn oluwọde logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020 ni Lekki Toll Gate.
''Ọpọ eeyan lo fẹran ki wọn maa gbe iroyin to buru jai nipa orilẹede Naijiria papaa julọ ileeṣẹ ologun oriilẹ fun gbogbo agbaye,'' Brig. Gen. Taiwo lo sọ bẹẹ.
- Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìsìnkú Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó tó kú lẹ́ni ọdún 36
- Ṣe lóòtọ́ ni ejò ń pọ owó fún Ginimbi, ọ̀dọ́mọdé olówó kó tó jáde láyé?
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Àwọn oniròyìn ló tú àṣírí ààbò Prof Peller, tí wọn fi ri pa - Lady Peller
Ọgagun Taiwo ni ''laipẹ yii ni DJ Switch ke gbajare pe ileeṣẹ ologun n wa oun, eleyi ti ko ri bẹẹ rara.''
O ni iṣẹ pọ fun awọn sọja lati ṣe nipinlẹ Eko ju ki wọn maa wa ẹnikan tabi eeyan meji kan kiri.
''Ko ye mi ibi ti DJ Switch ti gbọ wi pe ileeṣẹ ologun oriilẹ n wa,'' Brig. Gen. Taiwo lo sọ bẹẹ niwaju igbimọ oluwadii.
DJ Switch sọ tẹlẹ naa pe oun ṣe iranwọ lati yọ ọta ibọn to ba awọn olufẹhonuhan kan ni Lekki Toll Gate ninu fidio to fi sori oju opo Instagram rẹ.
Iroyin kan tiẹ sọ pe DJ Switch ti fi Naijiria silẹ lọ ṣe atipo nilẹ okeere lẹyin to sọ pe awọn eeyab kan n dunkoko mọ oun.