Bisi Alimi: Èmi tí mò ń tọrọ ilé gbé ní London, wá di onílé méjì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọrọ ifẹ bi adanwo ni lawọn Yoruba maa n wi. Eyi lo difa fun Bisi Alimi to fẹ ọkunrin ẹgbẹ rẹ, Anthony Davis gẹgẹ bi ọkọ.

Bisi Alimi, ẹni to n dupẹ lọwọ Eleduwa fun ayẹyẹ igbeyawo rẹ pẹlu Davis, to pe ọdun mẹrin lọjọ Aiku.

Alimi sọ loju opo Instagram rẹ pe, ko si ọna mii lati ṣayẹyẹ ọdun kẹrin igbeyawo oun ati Davis, ju bi awọn ṣe ṣẹṣẹ ra ile keji niluu London.

''Mi o le gbagbọ pe emi, to jẹ pe mi o rile gbe, ti awọn ọrẹ gba sile, lo wa di onile niluu London, ile ti kii ṣe ẹyọ kan amọ meji,'' Alimi lo sọ bẹẹ.

Alimi wa dupẹ lọwọ gbajugbaja agbohunsafẹfẹ nni, Funmi Iyanda, fun bo se gbaruku ti oun ninu irin-ajo aye rẹ.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn ọrẹ rẹ miran ti wọn ti ṣe iranwọ kan tabi omiran fun un.

Alimi tun rọ awọn eeyan lati mase kaarẹ pẹlu ohun ti wọn fẹ jẹ laye, o ni bo pẹ bo ya, yoo pada wa si imuṣẹ, bi wọn ko ba kaarẹ.

Ọgbẹni Alimi tun gbadura loju opo Instagram pe, oun ati ọkọ oun yoo ṣe ọpọlọpọ ọdun laye.