You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dino Melaye: Ẹ̀yin ara Ondo, ẹ kígbe pé kò fẹ́ èrú ìbò, kí ìbò yín má ba à wọmi
Sẹnatọ Dino Melaye to soju ẹkun idibo Iwọ Oorun Guusu Kogi nile asofin agba kẹjọ to kọja ti gba awọn eeyan ipinlẹ Ondo nimọran lati bẹrẹ si kigbe pe awọn tako eru ibo.
Melaye ni bibẹẹkọ awọn to fẹ yi ibo yoo yi esi ibo ọjọ Satide to n bọ mọ wọn lọwọ, ti wọn ko ba bẹrẹ si ni mu igbe bọnu bayii pe ki magomago ibo mase waye.
Dino Melaye gbe imọran yii kalẹ lori eto ileesẹ BBC Kan pẹlu afikun pe bi ariwo tawọn eeyan ipinlẹ Edo pa lati tako ibo yiyi lo jẹ ki aseyọri ibo gomina waye nibẹ.
Bakan naa ni Sẹnatọ nile asofin agba kẹjọ naa tun gba awọn ọmọ Naijiria nimọran pe ki wọn mase maa gbẹnu dakẹ, amọ ki wọn pariwo sita lati tako awọn igbesẹ ijọba ti ko ba dun mọ wọn ninu.
"Dipo ki ijọba maa bẹru araalu to gbe wọn sipo, araalu lo n bẹru ijọba bayii nitori ibẹru ti ijọba ti gbin sọkan wọn, wsn ko si fẹ ku tabi lọ si atimọle.
Se ni ijọba tun n di kun ẹru araalu lasiko yii ti Coronavirus ti mu ki ọrọ aje ọpọ eeyan dẹnu kọlẹ, to si jẹ pe ara ilu lo n pese owo fun ijọba, dipo ki ijọba wa ọna ti yoo fi mu adinkun ba ajaga to wuwo to wa lọrun awọn araalu."
Melaye ni ẹẹmẹta ree tijọba ti safikun owo epo lati igba ti Coronavirus ti bẹrẹ, ti kii ba si se ijọba ti aarẹ n se, se o yẹ ko tun safikun owo ina ati owo ori ọja lasiko yii.
O wa gba ijọba nimọran lati jẹ ki eto atunto orilẹede yii tawọn araalu n beere fun waye bibẹẹ kọ, fun ara atunto ni yoo se ara rẹ, eyi to lee mu iyapa ati ipinya waye fun Naijiria.
Nigba to n sọrọ lori bawọn ọmọ orilẹede yii se n beere fun wiwọgile ẹka ọlọpaa SARS to n gbogun ti iwa idigunjale, asofin agba naa ni aarẹ Buhari funra rẹ lo yẹ ko bọ sita lati kede pe oun wọgile isẹ awọn SARs yii, bi bẹẹ kọ, iyipada kankan ko ni waye.
"Se bi igba kẹrin ree laarin ọdun mẹta ti wọn yoo kede pe awọn fofin de ẹka SARS amọ irọ lo wa nidi rẹ, o digba ti aarẹ ba sọrọ, ki wọn to mu isẹ se lori rẹ, gbogbo ohun tawọn ọlọpaa n sọ yẹ, irọ ni."
Nigba to n salaye ọna to gba ko ọrọ jọ, to fi di onile ati mọto rẹpẹtẹ, to si n wọ asọ asiko, Melaye ni oun ko lọwọ ninu iwa ọdaran, bẹẹ ni oun ko gba isẹ agbase lọdọ ijọba, nitori wọn ko ba ti ri idi oun.
"Isẹ to mọ ni mo n se. Mo n se katakara ilẹ ati ile, okoowo nilẹ yii ati loke okun, bẹẹ ni mo si tun nko ọja wọle. Ọdọ to ba si fẹ mọ nipa okoowo to lee tete mu owo wọle, lee kan si mi, to ba si jẹ pe mo n se mọkaruru ni, ijọba ko ba ti ridi mi."
Lakotan, Dino Melaye ni oun fẹran orin kikọ pupọ, to si seese lọjọ iwaju, ki oun gbe awo orin jade sita tabi ki oun di akọrin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé iṣẹ́ ń dúró de akẹ́kọ̀ọ́ tó yan iṣẹ́ olùkọ́ láàyò ní fásitì?
- Adájọ́ sọ wòlíì Sotitobire àtàwọn márùn-ún míì sẹ́wọ̀n gbére!
- Kìí ṣe emí ni mó ràn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ mi tó sọ̀rọ̀ abùkù sí FIBAN níṣẹ́- Wasiu Ayinde
- ENDSARS: Ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, ẹ ṣè ìrànwọ́ irinṣẹ́ fáwọn ọlọ́pàá- Naira Marley bẹ̀bẹ̀
- Ẹ̀wọ̀n ni wàá gbẹ̀yìn sí, kò sí bóo ṣe dọ́gbọ́n tó - Seyi Makinde wa ègúná ọ̀rọ̀ lé Fayose
- Ibadan ń jó àjórẹ̀yìn láàrin ẹgbẹ́, ẹ fún wa ní ìpínlẹ̀ tiwa - Kola Balogun bẹ ilé aṣòfin
"Orin wa ninu ẹjẹ mi, Ọlọrun si lo fi ami ororo yan mi lati maa kọrin, ọna kan ree ti mo si n gba lati fi ọrọ ransẹ sawọn eeyan, bẹẹ ni orin n sisẹ ti mo n ran-an."
Bakan naa lo fikun pe olootọ ẹda ni oun, ẹni to korira ka maa fi dudu pe funfun, iwa otitọ yii si ni oun yoo maa sọ titi lai naani inu ẹgbẹ oselu ti oun wa.