FG Survival Fund: Wo bi o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ láti j'ànfàání owó ìrànwọ́ ìjọba Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi oníṣẹ́ ọwọ́, oníṣẹ́ àdáni àti awakọ̀

Awọn oniṣẹ ọwọ, ati ọlọkọ eero, ni ọpọn sun kan ninu eto owo iranwọ ti ijọba Naijiria n ṣe nitori aarun Covid-19.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni wọn ṣe ifilọlẹ eto naa fun ipele tuntun yii.

Gẹgẹ bi ikede ti awọn alamojuto eto naa fi sita, iranwọ naa wa fun awọn olokoowo adana kekeeke jakejado Naijiria, lati tu wọn lara fun owo ti wọn padanu nitori itankalẹ aarun coronavirus ni lara ọrọ aje wọn ku.

Eto naa ti bẹrẹ fun awọn olokoowo ni ẹka eto ẹkọ, irinajo afẹ, ati awọn miran, ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2020, yoo si pari ni ọjọ kẹkdogun, oṣu Kẹwaa.

Fun awọn oniṣẹ ọwọ ati awọn ọlọkọ eero, ẹgbẹrun mẹtalelaadoje (333,000) ni yoo jẹ anfaani lara owo ti ijọba fẹ ẹ fun wọn.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ni ijọba yoo fun ẹni kọọkan wọn.

Wo bi iforukọsilẹ yoo ṣe lọ

Awọn alamojuto eto naa sọ pe isọri mẹta ni wọn yoo pin awọn oniṣẹ ọwọ ati ọlọkọ eero naa si.

Awọn to wa ni isọri kinni yoo ṣe iforukọsilẹ ni ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa.

Awọn ipinlẹ to si wa ni isọri kinni ni:

•Abuja

•Lagos

•Kaduna

•Ogun

•Kano

•Anambra

•Borno

•Bauchi

•Abia

•Rivers

•Plateau

•Delta

Ipinlẹ mejila ni yoo kopa ni isọri keji. Wọn o si bẹrẹ eto ti wọn ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa.

Ọjọ kẹsan, oṣu Kọkanla si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ni isọri kẹta yoo kan ipinlẹ mẹtala to ku.

Wo awọn ilana ti wa a tẹle lati kopa

O gbọdọ jẹ olokoowo kekere (to ni oṣiṣẹ) tabi oniṣẹ adani

Ida marunlelogoji (45%) awọn ti yoo jẹ anfaani eto naa ni yoo jẹ obinrin, ida marun yoo si jẹ awọn akanda ẹda.

To ba jẹ ileeṣẹ, o gbọdọ ti fi orukọ silẹ lọdọ ajọ to n mojuto ọrọ awọn ileeṣẹ, Corporate Affairs Commission; o gbọdọ ni to oṣiṣẹ mẹta; bakan naa ni ọga ilẹẹṣẹ naa gbọdọ jẹ ọmọ Naijiria, to ni nọmba BVN.

Fun awọn oniṣẹ adani, awọn awakọ bọọsi, awakọ takisi, to fi mọ awọn takisi igbalode bi i Uber ati Bolt, ati awọn mọkaliiki.

Awọn oniṣẹ ọwọ bi birikila, jorin-jorin, ati bẹẹbẹẹ lọ, ni eto naa kan.