Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Saudi Arabia ti kéde pé ètò Umrah yóò bẹ̀rẹ̀ padà lẹẹ́yìn oṣù bí mẹ̀fà ti wọ́n ti fòfide e

Ijọba sọ pe lati ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa ni awọn to n gbe ni orilẹ-ede naa yoo ni anfaani lati bẹrẹ eto adura Umrah, ti awọn to n gbe nilẹ okeere yoo

si le bẹrẹ ti wọn ni ọjọ kinni, oṣu Kọkanla.

Sugbọn ṣa, wọn ni adinku yoo ba iye eeyan to le kóra jọ pọ lẹẹkan naa. Bakan naa ni yoo loju àwọn ọmọ orilẹ-ede ti wọn yoo gba laaye lati kopa.

Ileesẹ to wa fun ọrọ abẹle ni Saudi Arabia ni ti ajakalẹ aarun coronavirus ba ti kasẹ nilẹ ni wọn o to o gba gbogbo eeyan laaye jakejado agbaye.

Ọdọọdún ni awọn Musulumi kaakiri agbaye ma n lọ si orilẹ-ede Saudi Arabia fun eto adura Umrah, to jẹ irinajo mimọ keji ninu ẹsin Isilaamu.

Àmọ́ o, asiko to ba wu ẹni kọọkan lo le rinrinajo naa, yatọ si Hajj to jẹ ẹẹkan lọdun.

Ẹgbẹrun mẹwaa eeyan pere lo kopa ni Hajj ọdun 2020, dipo bi miliọnu meji to ma n kopa lọdọdun.

Lara ilana ti awọn alasẹ tun la silẹ ni pe ẹgbẹrun mẹrin eniyan ni yoo le kopa lojoojumọ fun Umrah lati ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa.

Ti yoo si di ẹgbẹrun lọna ogun ninu oṣu Kọkanla, ti wọn ba ti ṣi anfaani silẹ fun awọn ọmọ ilẹ okeere.