You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilorin Rainstorm: Àwọn olùgbé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjoba lẹ́yìn tí ìjì òjò tó rọ̀ nílùú Ilorin ba ńkan púpọ̀ jẹ́
Eeyan kan ti ku ninu iṣẹlẹ ojo alatẹgun to rọ nilu Ilorin ti awọn ọmọde meji kan si ti di awati lẹyin tomi gbe wọn lọ.
Eeyan kan mii ti orule ile wo lu mọlẹ n gba itọju lọwọ nile iwosan gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ti sọ fun BBC.
Ileeṣẹ panapana ilu Ilorin lo fi idi ọrọ yi mulẹ fun akọroyin BBC Yoruba.
- Obaseki la Ize-Iyamu mọ́lẹ̀ wọlé ìbò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ìpínlẹ̀ Edo
- Ọ̀tọ̀ lórìn bi wọ́n ṣe yan àwọn ti yóò kúrò nílé ẹlẹ́gbọ̀n ọ́n àgbà BB Naija lónìí
- 'Mo mọ̀ọ́mọ̀ sin ọmọ-ọmọ mi, ìkókó jòjòló láàyè ni, nítorí wọ́n fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ ló fi lóyún rẹ̀'!
- Trikytee àti Ozo ní wọ́n di ẹrù ilé lé lórí nilé bbnaija lọ́sẹ̀ yìí
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana to wa ni adugbo Folawiyo Ilorin, ọgbẹni Abdulkareem Jimoh ni ladugbo Ita Egba-Ita Ogunbo ni eeyan kan ti ku.
''A gba ipe ni alẹ ọjọ Abamẹta pe ile ti wo mọlẹ mọ awọn eeyan meji kan.
Nigba ti a de ibẹ, a ribi doola ẹnikan, ẹnikeji si padanu ẹmi rẹ''
Ọgbẹni Jimoh tẹsiwaju pe omi gbe awọn ọmọde meji lọ, ọkunrin kan ati obinrin kan ladugbo Emirs Road ati ni Gaa Odota.
''Ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹwaa ni omi gbe lọ ni Odota ti ọmọ obinrin ọmọ ọdun mejila si ko si omi ni Emirs road.''
O salaye pe awọn ko ti i ri oku awọn ọmọ naa titi di asiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yi.
Sugbọn awọn ṣi n wa wọn.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Awọn olugbe ilu Ilorin ti n rawọ ẹbẹ si ijọba lati ṣe iranwọ fun wọn lẹyin ti iji ojo ṣe akoba fun dukia loru mọjumọ ọjọ Aiku.
Niṣe ni orule ọpọ ile ati ṣọọbu itaja ṣi danu ti awọn ile ati alapa ogiri laarin awọn agbo ile mii si wo danu.
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan n pin aworan oṣẹ ti ojo naa ṣe ladugbo bi Alore, Ọmọda, Oko Olowo, Oju Ekuun ati Ita Ogunbọ.
Opo ina pupọ to fi mọ orule awọn ile ni ojo yi bajẹ ti ọpọ si ti di alainile lori bayi ni Ilorin.
Ijọba Ipinlẹ Kwara ninu atẹjade kan ti Rafiu Ajakaiye, agbẹnusọ Gomina fi sita ti ṣe agbekalẹ igbimọ pajawiri lati ṣe iranwọ fara ilu.
Ajakaiye ni niṣe ni iroyin ijamba ti ojo naa ṣe mu ibanujẹ ba ọkan Gomina Abdulrahaman Abdulrazaq.
O ni Gomina ti paṣẹ ki wọn tete bẹrẹ iṣẹ lati gbe awọn opo ina ti ojo bajẹ dide lati le dena aburu mii.
Yatọ si iṣẹlẹ yi to waye awọn eeyan ipinlẹ Kwara paapa ni agbegbe ariwa ipinlẹ naa bi Pategi, Tsonga, Tsaragi ati Lade n koju omiyale agbara ya ṣọọbu.
Kwara wa lara awọn ipinlẹ ti ajọ to n ṣeto bi oju ọjọ ti ṣe ri ni yoo koju ipenija arọrọda ojo lọdun yi.