You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Airforce shortlist 2020: Iléeṣẹ́ ọmọogun òfúrufú kéde orúkọ àwọn tó yege ìdánwò àṣewọ'léeṣẹ́ ológun náà
Ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria ti gbe orukọ awọn eeyan to yege ninu idanwo aṣewọle si ileeṣẹ naa jade.
Ni aṣalẹ Ọjọbọ ni ileeṣẹ ọmọogun ofurufu gbe orukọ wọn jade loju opo Twitter rẹ.
O wa rọ awọn eeyan to dije fun idanwo aṣewọle si ileeeṣẹ ọmọogun ofurufu 2020 airmen/airwomen recruitment lati lọ yẹ orukọ wọn wo.
Bakan naa ni wọn tun jẹ ko di mimọ fun awọn to ba yege pe ki wọn gbaradi fun ifọrọwanilẹnuwo ti yoo waye ni ibudo ọmọ ogun ofurufu to wa ni Kawo ni ipinlẹ Kaduna, iyẹn NAF Base, Kawo - Kaduna laarin ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan si ọjọ kejila oṣu kọkanla ọdun 2020.
Awọn nnkan ti wọn ni awọn to ba yege fun ifọrọwanilẹnuwo naa yoo mu dani niwọnyi :
- Ojulowo ati ẹda iwe ẹri wọn gbogbo (Originals & Photocopies of their Credentials)
- Aṣọ amuṣere idaraya meji (2 White Vests)
- Soko penpe awọ olomi buluu meji (2 Blue PT Shorts)
- Bata amuṣere idaraya, Canvas kan, (One Pair of Canvas Shoes)
- Aworan pelebe passport mẹrin.(4 Passport Photographs)
- Iboju Facemask (Face Masks)
- Ati oogun apakokoro ọwọ Hand sanitizer (Hand Sanitizer)