You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ado Ekiti murder: Ìbẹ̀rù-bojo l'Ado Ekiti lẹ́yìn táwọn agbébọn pa ọ̀gá àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀
Ibẹru-bojo ti gbalẹ kan lagbegbe Odo Ado niluu Ado-Ekiti, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ekiti lẹyin ti awọn agbebọn kan yinbọn pa oludari ajọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni David Jejelowo.
Iṣẹlẹ naa ni a gbọ pe o ṣẹlẹ nile Ọgbẹni Jejelowo lọganjọ oru ọjọ Aje ọkọ kẹrinla oṣu kẹsan an lopopona Umesi, Igirigiri niluu Ado Ekiti.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ṣalaye pe wọn ti gbe oku ọkunrin naa sile igboku si nile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ipinlẹ Ekiti.
- Ọmọkùnrin tó ya 'Blue film' nínú igbó Osun Osogbo ti bayé ara rẹ̀ jẹ́ - Yemi Elebuibon
- Obasanjo gan an ló ń ṣe ìpínyà Nàìjíríà, Buhari ló ń tún ṣe -Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Ó yẹ kí Sotitobire gbọ́ ìdájọ́ lónìí ṣùgbọ́n ẹ wo bí ilé ẹjọ́ ṣe tún ṣe é
- Àjọ ọlọpàá Eko kédé pé ìbalòpọ̀ nítà kò bójúmu
- Àwọn ọ̀nà tí obìnrin fi le gbádùn ìbálòpọ̀
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun ti awọn agbebọn naa ni lọkan ti wọn fi ṣekupa Ọgbẹni Jejelowo.
Abutu fidi rẹ mulẹ pe ninu yara Ọgbẹni Jejelowo ni awọn kọlọ nbiti ẹda ọhun ti dabọn bo ọkunrin naa.
O ni iwadii lo maa fihan bo ya adigunjale lawọn agbebọn ọhun tabi agbenipa ni wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa fi da awọn araalu loju pe awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa yoo foju wina ofin ti ọwọ ba tẹ wọn tan.