Lagos-Ogun Train wreck: Reluwé kọlu ọkọ̀ mẹ́ta l'Eko, èèyàn méjì kú, méje fara pa

Ọkọ mẹta ni reluwe to gbera lati ipinlẹ Ogun wa si ilu Eko ni owurọ ajọ Aje kọlu ninu irinajo rẹ.

Ajọ to n ṣe kokaari iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ṣalaye pe ọkọ Jiipu Highlander ni ọkọ kẹta ti reluwe naa kọlu ti awọn mẹta to wa ninu rẹ fara pa yannayanna ti wọn si gbe wọn lọ si ileewosan nla LUTH fun itọju.

Ọkan ninu wọn lo kọkọ jade laye ti ẹni keji ṣi n gba itọju ni ileewosan naa.

Ṣugbọn ajọ LASEMA ti fidi rẹ mulẹ pe ẹnikeji naa ti pada dagbere faye.

ọkọ akero bọọsi kan ati ọkọ ayọkẹlẹ jiipu miran ni reluwe naa kọkọ kọlu lagbegbe Oshodi.

Eeyan mẹfa lo wa ninu bọọsi funfun naa.

Reluwe naa la gbọ pe o wọ awọn ọkọ mejeeji naa fun ọpọlọpọ irin ko to di pe o duro.

Ọkọ oju irin Reluwee naa kọlu ọkọ bọọsi akero lagbegbe Oshodi ni ilu Eko lowurọ ọjọ Aje.

Ọrọ ọhun di wọlukọlu lagbegbe abẹ bridge ni Osodi.

Ọkọ reluwe ọhun to n gbera lati ipinlẹ Ogun wa si ilu Eko ni irinajo reluwe akọkọ ti yoo waye laarin oṣu marun un ti wọn ti ijọba ti ti irinna ojuirin nitori ajakalẹ arun COVID-19.

Kii ṣe iroyin mọ pe ọpọ igba lawọn eeyan maa n gbe ọja si oju irin, bẹẹ lawọn ọkọ a maa fo oju opo irin reluwe bi o ṣe wu wọn eyi to si ti mu ẹmi ọpọlọpọ lọ lorilẹede Naijiria.

Ajọ to n ṣe kokaari iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ṣalaye pe ọkọ ti reluwe naa kọlu jẹ bọọsi alawọ funfun kan ti nọmba idamọ rẹ jẹ GGE 972 GE lagbegbe PWD l'Oshodi.

Ajọ naa ni ko si ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ ati pe wọn ti kgbe ọkọ naa kuro loju irin bẹẹni reluwe naa ti tẹsiwaju irinajo rẹ.

Ẹwẹ, ọkọ reluwe naa la tun gbọ pe o kọlu ọkọ ayọkẹlẹ miran ni agbegbe Arena Gate ni Oshodi kan naa.