Zambia Rats Video: Fọ́nrán fídíò èkúté ní ilé ìwòsan jẹ́ ìdójútì fún ìjọba -Mínísítà ìlera

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Fọnran fidio kan to lu sita lori ayelujara ti mu ki awọn alakoso ile iwosan kan ni Zambia wọ gau.

Ninu fidio taa n wi yi, niṣe lawọn ekute n da igba ru ninu lẹda kan ti wọn gbe kalẹ lẹgbẹ ibusun alaisan.

Ile iwosan Kitwe Central Hospital to wa ni agbegbe Copperbelt nilẹ naa jẹ ọkan lara awọn ile iwosan to tobi julọ.

Ọrọ yi to de'ti igbọ Minisita feto ilera, Chilatu Chilufaya, ti mu ki o ṣabẹwo pajawiri sile iwosan naa.

Abalọ ababọ abẹwo yi ni pe o ni ki wọn gbe igbesẹ ijiya to tọ lori oludari ile iwosan ọhun.

Minisita Chilufaya sọ pe idojuti nla ni isẹlẹ yi jẹ si ijọba nitori naa gbogbo awọn ti igba ibajẹ fidio yi ṣi mọ lori ko ni lọ lai jiya.

Loju opo Twitter, niṣe lawọn eeyan orileede naa n bẹnu atẹ lu awọn ijọba ati alakoso ile iwosan naa.