You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Rwanda Genocide: Òbí ni mi - sùgbọ́n mo pa òbí àwọn ọmọ ọlọ́mọ
Ẹgbẹlẹgbẹ awọn obinrin lo kopa ninu ipaniyan abẹle to waye ni Ruwanda lọdun 1994 subgọn ko si ẹni to sọrọ nipa wọn ati bi wọn ṣe n ṣe atunṣe pẹlu ẹbi wọn.
Akọròyìn Natalia Ojewska ti n ba awọn obinrin kan to kopa ninu isẹlẹ naa sọrọ ni ọgba ẹwọn.
Irinajo lati lọ pọnmi fun ina dida ounjẹ aarọ lasan wa di ǹkan ti Fortunate Mukankuranga daran ipaniyan si.
Ninu asọ ọgba ẹwọn alawọ omi ọsan lowa to ti n sọrọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye lowurọ kutu ọjọ kẹwa oṣu kẹrin ọdun 1994.
Bí o ṣe n lọ lori ti awọn kan bẹrẹ si ni lu awọn ọkunrin meji kan laarin ọna.
" Nigba ti awọn meji naa subu lulẹ. Mo mu igi mo wa so pe Iku lo tọ si Tutsis!'.
Mo fi igi gba ọkan ninu wọn ati ikeji... mo wa lara awọn apaniya, " ẹni ọdun aadọrin ọun lo sọ bẹ.
Ipaniyan ti mo ṣe n le mi kiri
Meji niyi ninu awọn ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin awọn ẹya Tutsis àti diẹ ninu awon Hutus ti wahala naa si waye fun ọgọrun ọjọ.
Lẹyin ikopa rẹ ninu ipaniyan yii Mukankuranga to jẹ ẹya Hutus pada sile lọdọ awọn ọmọ rẹ meje pẹlu irobinujẹ ọkan, tí ọkan rẹ ba tun lọ si bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, oun jẹ lọkan gidi.
" Abiyamọ ni mi , mo si pa obi awọn ọmọ kan," bẹẹ lo sọ.
Lẹyi ọjọ meji ti iṣẹlẹ yii ṣe ni awọn ọmọ ẹya Tutsis meji ti wọn ti pa obi wọn yọju de lẹnu ọnà mi pe ki n jẹ ki a ti awọn fara pamọ sọdọ mi.
Igbekun itiju
Ko roo lẹẹmeji to fi fiwọn pamọ, bayii ni iku si ṣe fori awọn ọmọ naa.
" Botilẹ jẹ pe mo doola ẹmi awọn ọmọ naa, mo kuna lori awọ ọkunrin meji akọkọ. Iranwọ ti mo ṣe ko le fd ọwọ ago pada sẹyin gẹgẹ bi Mukankuranga ṣe sọ
O jẹ ọkan lara awọn obinrin ẹgbẹrun mẹrindinlọgọrun ti ijọba ju sẹwọn fun ipa wọn ninu ipaniyan abẹle Ruwanda- awọn miran pa agbalagba bi ti Mukankuranga awọn miran p ọmọ wẹwẹ, nigba ti awọn kan fi anfani naa fipa bawọn eniyan lopọ ti wọn si tun gbẹmi wọn.
Ní alẹ ọjọ kẹfa oṣu kẹrin ọdun 1994, ni àwọn kan yin baa lu to n gbe aarẹ Rwanda to jẹ ẹya Hutu nibọn Juvental Habyarimana bi o ṣe n fẹ ba ni papakọ ofurufu ni Kigali.
Botile jẹpe ko si ẹni to mọ ẹni to se iṣẹ nla ibi naa bayii ni awọn ajajagbara Hutu bẹrẹ si ni naka alebu si àwọn alatako ijọba Hutsi ti wahala si bẹrẹ, laarin wakati diẹ ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ Hutus ti wọn ti n lodi si ẹya hutsi fun ọpọ ọdun darapọ ti wọn si bẹrẹ ipaniyan.
Awọn obinrin naa kopa ti wọn pe ara wọn ni obinrin Rwanda ti wọn si n saabo fun awọn obinrin.
"O nira ki oye rẹ to ye ni pe bawo ni iya to nifẹ ọmọ rẹ yoo ṣe wa lo si ile aladugbo rẹ lati pa ọmọ rẹ bi Regine Abanyuze ṣe sọ, òṣìṣẹ "Never again" ile iṣẹ ti kii se ti ijọba ti wọn si wà fún ipese alaafia ati ipẹtu sawọ.
Ní kete ti ija ọhun bẹrẹ bayii, ẹgbẹgbẹrun obinrin lo sọ ara wọn di agabatẹru iwa ipa pẹlu awọn obinrin.
Ipa meji ti ipaniyan naa jasi
Martha Mukamushinzimana ọlọmọ marun, ti oun nikan da ẹru ẹṣẹ gbe fun ọdun marundinlogun, ki o to lọ salaye ara rẹ fun ile ẹjọ lọdun 2009 nigba ti ko le koju isoro ẹdun ọkan yii.
Ọpọ awọn obinrin yii ni eri ọkan ipaniyan yii n da laamu nitori wọn kuna ojuṣe wọn gẹgẹ bi abiyamọ.
" Asiko ni eroja idapadabọsipo ti a n lo julọ, a n fun wọn ni aaye yii bi o ti tọ ati bo tiyẹ titi ti wọn yoo fi wa jẹwọ nkan ti wọn ti ṣe gẹgẹ bi Grace Ndawanyi adari ọgba ẹwọn awọn obinrin ni Ngoma ni Rwanda.
" Nitori ile mi sun mọ ẹgbẹ titi mọ maa n gbọ fere awọn Tutsi bi wọn se n ko awọn eniyan lo si ileijọsin gẹgé bi Mukamushinzimana ṣe sọ nibi to joko si ni kọrọ ọgba ẹwọn pẹlu omije lọwọ.
Ẹgbẹgbẹrun awọn Tutsis ni wọn n rọpọ si ẹgbẹ kan ni ijọ Aguda ẹka Nyamasheke, ti wọn si jijadu ẹmi wọn fun ọṣẹ kan gbako, bi afoju ri Stanislus Kayitera to ti pe ọdun mẹtaleláàdọta bayii jẹ ọkan lara awọn to ru iṣẹlẹ naa la pẹlu awọn oniruuru apa lara .
" Mo ranti awọn obinrin ti wọn n gba okuta ti wọn si n fun ọkunrin ti wọn si n lẹẹ mọ wa. Bakna naa ni awọn ọkunrin naa n yinbọn ti wọn sin da epo sawọn eniyan lara ti wọn n sun wọn nina.
" Wọn wọ sọọsi ti wọn bẹrẹ si ni sa wa ni ada ti wọn si n pa awọn eniyan, eri ọgbẹni Kayitera ti oun naa bọ lọwọ ogun naa ree nítori o sa pamọ saarin awọn oku.
" Mo gbe ọmọ mi ọmọ ọṣẹ meji meji sẹyin mo darapọ mọ àwọn obinrin to n fun awọn ọkunrin ni okuta lati pa awọn eniyan, eyi ni alaye Mukamushinzimana nitori pe o ni wọn paa lasẹ fun-un ni.
Nigba ti wọn juu sẹwọn lọdun 2009 ko si ẹbi rẹ kan to bẹẹ wo bakan naa ko ṣẹni to ba tọ awọn ọmọ rẹ mararun.
Mi o le dá omije oju mi duro
Fortunate Mukankuranga ni igboya lati jẹwọ ẹsẹ rẹ lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti dajọ rẹ lọdun 2007.
O oun ranti pe ninu ibẹru bojo ni oun wa ti oun fi pe ọkan ninu awọn ọmọ ẹni ti o pa to si jẹwọ fun pe ki o fori ji oun.
Lodi si ero mi, " inu rẹ dun ọkan rẹ si balẹ nigba to ri mi mi o si le pa omije oju mi mọra bi mo se di mọọ
Mukankuranga wa n wo ọjọ iwaju pẹlu ironu ọtun pe o ṣeeṣe\ki oun le ri atunse si ibasepọ pẹlu ẹbi rẹ.
" Ti mo ba pada dele ma maa gbe igbe aye alafia pẹlu awọn ẹbi mi, n o nifẹ wọn ju ti atẹyinwaa lọ bakan naa ni maa bikita nipa awọn eniyan. Mo n jiya ẹsẹ ti mo ṣẹ ni, ko yẹ ki n wa lẹwọn bi mo ṣe jẹ abiyamọ, o fi kun