Sola Kosoko: Ẹ tẹ ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lòpọ̀ ní ọ̀dá, ìwà ìkà ni

Gbajumọ oṣere tiata lobinrin, Sola Kosoko Abina ti sọ fun araye pe, baba oun, Jide Kosoko, ti oun naa jẹ agba ọjẹ osere tiata, lo ṣe agbatẹru bi oun ṣe de idi isẹ naa.

Sola Kosoko, ẹni to sísọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto BBC Yoruba, tun fikun un pe ọla abata tii mu odo san ni ọrọ oun ninu isẹ tiata.

O ni "agbẹjọro abi agbohunsafẹfẹ ni n ko ba jẹ, ka ni n ko ba baba mi ṣe iṣẹ tiata, nitori lẹyin ile ẹkọ girama ni wọn ti ṣe iwuri fun mi lati maa kopa ninu ere ."

Gbajumọ oṣere tiata naa tun salaye pe lootọ ni wọn maa n kọ ẹnu ifẹ si obìnrin ninu iṣẹ tiata bi awọn akẹẹgbẹ oun kan ti n sọ amọ kii ṣe tipatipa.

Amọ ko sai yan pe kii ṣe inu iṣẹ tiata nìkan ni wọn ti n kọ ẹnu ifẹ si obìnrin nitori o wa kaakiri, ti awọn obinrin miran si maa n pa irọ nigba mii.

Nigba to n sọ ero rẹ lori iwa ifipa bani lopọ to n gogo nilẹ wa lẹnu lọ lọọ yii, Sola ni ẹni ti ori rẹ ko pe lo n fi tipa ba obìnrin lopọ, tori wọn ni agbara lati kọ ẹnu si obìnrin to ba wu wọn.

Sola Kosoko ni: "Ṣe lo yẹ ki ijọba maa tẹ awọn ọkunrin to ba fipa ba obinrin lopọ ni ọda lọna ati fi wọn jofin, eyi ti yoo mu wọn dẹkun iwa ika ati ipaniyan naa,

O ni eyi dara nitori iwa ifipa bani lopọ kii kuro ni ọpọlọ obinrin laelae, bi o tilẹ jẹ pe awọn obinrin agbaaya kan naa wa, to n fi tipa ba awọn ọmọdekunrin sun."

Sola Kosoko wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe, ko si ẹṣin ti oun ko le ṣin nitori ẹlẹṣin.

Kristẹni ni oun, ọkọ oun jẹ musulumi, iya oun naa jẹ musulumi, baba oun jẹ Kristẹni, ti iya baba oun si jẹ musulumi, nigba ti baba baba oun si jẹ Kristẹni.