Ogun Suicide: Ọlọ́pàá ní iwádìí ṣì ń lọ lórí bóyá ìyàwó ló sokùnfà bí ọkọ rẹ̀ ṣe pokùnso

Àkọlé fídíò, Ogun: Ọlọ́pàá ní iwádìí ṣì ń lórí bóyá ìyàwó ló sokùnfà bí ọkọ rẹ̀ ṣe pokùnso

Baale ile kan ni agbegbe Sango Ota ni ipinlẹ Ogun ti pokunso lẹyin ti oun ati iyawo rẹ tahun si ara wọn, to si wọle lọ.

Ọmọ Oloogbe naa ni oun mura lati lọ gba owo ounjẹ lọwọ Baba oun ni oun ba wọn ni ibi ti wọn pokunso si.

Ọmọ naa ni ọpọlọpọ igba ni baba oun ati iya oun ti maa n ja ati wi pe isẹlẹ naa waye ni ọjọ keji ti wọn de lati agọ ọlọpaa ni ibi ti wọn ti lọ pari ija fun wọn.

Bakan naa ni awọn ará àdúgbò sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa baalé ilé tó pokùnso nítorí ìjà pẹ̀lú olúlùfẹ́ rẹ̀ naa.

Amọ, Agbẹnusọ fun ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi to fi idi ọrọ naa mulẹ ni iwadii si n lọ lọwọ lori pe boya iyawo rẹ lo pa a abi kii ṣe oun.