Coronavirus in Ibadan: Àbẹ̀wò BBC sí iléeṣẹ́ "ISON Xperiences" tí òṣìṣẹ́ 78 ti kó àrùn coronavirus nílùú Ìbàdàn

Aja ikeji ati ikẹta ile yii to n bẹ ni agbegbe OLD KINGSWAY BUILDING DUGBE, IBADAN ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣe awari oṣiṣẹ bii mejidinlọgọrin to lugbadi aarun Corona.

Ileeṣẹ ti awọn oṣiṣẹ naa n ṣiṣẹ fun ni wọn pe ni "ISON Xperiences" gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ṣe kede rẹ lọsẹ yii, aṣoju sini ileeṣẹ naa je fun amojuto awon onibara ileeṣẹ ikansiraẹni bii Airtel ati MTN.

Ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si ayika ileeṣẹ naa; a si ṣe akiyesi wi pe ẹnu ọna abawọ ileeṣẹ naa ti di titi pa gẹgẹ bi awọn agbofinro ṣe duro wamuwamu ni oriṣiriṣi ikorita.

Ọpọlọpọ ilẹẹṣe ati ile itaja lo yii ileeṣẹ naa ka, pupọ wọn lo si n ba iṣẹ lọ gẹgẹ bi ẹni wi pe ohunkohun ko ṣẹlẹ ni agbegbe naa.

Lara awọn ileeṣẹ ati ile itaja to sunmọ ileeṣẹ naa pẹkipẹki ni ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ijọba Radio Nigeria, Premier Fm 93.5 to dojukọ ileeṣẹ ti wọn ti ri awọn oṣiṣẹ to lugbadi aarun Corona.

Awọn ileeṣẹ mii to n bẹ ni agbegbe naa ni ẹka banki agba ilẹ wa, CBN to n bẹ ni agbegbe Dugbe niluu Ibadan, ile itaja nla Shoprite naa ko gbẹyin ni agbegbe naa.

Awa aladugbo ti wọn ni ki a fi orukọ bo awọn laṣiri kọminu lori ile itaja Shoprite pẹlu alaye wi pe oṣeeṣe ki awọn oṣiṣẹ to lugbadi aarun naa maa ra nnkan nile itaja naa.

Ẹlomii to ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe awọn aṣoju ajọ to n mojuto itankalẹ aarun, NCDC ṣe abẹwo si ileeṣẹ ti aarun naa ti foju han lati fin oogun apakokoro yika ile naa.

Saaju ni awọn olugbe agbegbe na kọ iwe ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ lati wa ṣe afọmọ gbogbo agbegbe naa nitori ibẹrubojo to rọ mọ awari awọn oṣiṣẹ to lugbadi aarun Corona.

Awọn oṣiṣẹ to ṣiṣẹ ni ileeṣẹ naa ko din ni ẹẹdẹgbẹta, ninu awọn perete ti ijọba ṣe ayẹwo fun sini ni wọn ti ri onka awọn eeyan bii ọgọrin to ti fi ara ko aarun naa.

Alaye ijọba ipinlẹ Ọyọ ni wi pe ayẹwo ṣi n tẹsiwaju.