You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àkòjọpọ́ àwọn nkan tó ṣẹ́lẹ̀ lágbo tíátà Yoruba lọ́sẹ̀ yìí
Awọn oṣere Yollywood ti dawọ sinima yiya duro bayii nitori itankalẹ aarun coronavirus.
Alaga ẹgbẹ TAMPAN, to jẹ agbarijọpọ awọn oṣere tiata, Alagba Bolaji Amusan, Mr Latin lo fi ikede naa sita lori ayelujara Instagram rẹ.
Mr Latin sọ ninu fidio naa pe ati ẹgbẹ TAMPAN ati ẹgbẹ awọn alagbata sinima fi ẹnu ko nibi ipade kan ti wọn ṣe lọjọ lọsẹ yii pe osere kankan ko gbọdọ ya sinima kankan lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin ọdun 2020.
O sọ pe awọn ṣe bẹ nitori itankalẹ aarun coronavirus.
Bakan naa lo sọ pe ida ẹgbẹ yoo ge oṣere yoowu to ba ru ofin naa.
Ninu iroyin miran, gbaju-gbaja oṣere to tun jẹ olokoowo, Lizzy Anjorin sọ pe itankalẹ aarun coronavirus ko le da ọja tita oun duro.
Ninu fidio kan to fi sita lori Instagram lo ti sọ bẹ, to si tun gba awọn ololufẹ rẹ ni imọran lati ṣe bakan naa nitori ebi.
Koda, o rọ wọn lati ṣe ajọpin ounjẹ de ọdọ awọn alaini.
Itankalẹ aarun coronavirus ko da ayẹyẹ ọjọ ibi awọn oṣere kan duro l'ọsẹ yii.
Lara awọn ti ọjọ ibi wọn ko ọni ọsẹ yii ni:
Regina Chukwu ṣe ọjọ ibi. Arẹwa obinrin naa sọ pe Ọlọrun nikan lo ye bi ọrọ aye oun ṣe n lọ.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta ni ọjọ ibi rẹ.
Kii wa a ṣe Regina nikan lo da ni ọjọ naa o.
Bakan naa ni arẹwa obinrin, Oyebade Adebimpe naa pe ọdun miran loke eepẹ. Koda, aarun coronavirus ko da ayẹyẹ duro. Awọn eniyan buta sẹnu nibi ayẹyẹ ọjọ ibi.
Ọjọ naa gan an ni ọjọ ibi agba oṣere, Aina Gold. Ninu fidio kan to fi sita, niṣe ni awọn ọrẹ rẹ fi omi wẹ ẹ lati ṣajọyọ ọjọ naa.
Gbaju-gbaja oludari ere, Adebayo Tijani naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi. Bakan naa ni arẹwa obinrin, Lola Margaret naa tun dupẹ pe oju oun ri ọdun miran loke eepẹ.
Agba oṣerebinrin, Joke Muyiwa ṣọjọ ibi tiẹ naa lọsẹ yii, ọmọ rẹ tun bimọ tuntun.
Oṣere naa ko le pa idunnu rẹ mọra rara. Ninu ọrọ to fi sita, o sọ pe ẹbun ọjọ ibi to ṣe iyebiye ju ni ọmọ tuntun naa jẹ fun oun.