Coronavirus in Nigeria: Èèyàn méje l'Eko, mẹ́ta l'Abuja kó àrùn Coronavirus

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Eeyan mẹwaa miran ni wọn tun ti ṣawari bayii pe wọn ni aarun Coronavirus.

Gẹgẹ bi iroyin kan ti minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria Dokita Osagie Ehanire ṣe fi sita loju opo twitter rẹ lọjọ Abamẹta.

Eyi ti mu iye awọn to ni arun yii lorilẹede Naijiria bayii di mejilelogun.

Ninu atẹjade naa, Minisita feto ilera ṣalaye pe mẹsan ninu awọn eeyan mẹwaa tuntun to ni arun naa lo jẹ ọmọ Naijiria ti wọn ṣẹṣẹ de lati orilẹede Canada, France, Netherlands, Spain ati ilẹ Gẹẹsi.

Eeyan kan yooku jẹ ẹni to ti ni ajọṣepọ pẹlu ọkan lara awọn eeyan to ti ni arun naa.

Awọn meje ninu awọn mẹwaa ti wọn ṣẹṣẹ ṣawari naa ni wọn wa lati ilu Eko, mẹta lati ilu Abuja.

O fi kun un pe gbogbo awọn eeyan naa ni wọn n gba itọju to peye lọwọ bayii.

Ni bayii mẹrindinlogun ninu awọn mejilelogun to ti ni arun yii lorilẹede Naijiria ni wọn wa lati ipinlẹ Eko, mẹta lati olu ilu Naijiria, Abuja, meji lati ipinlẹ Ogun, Ẹyọkan lati ipinlẹ Ekiti.

Dokita Ehanire jẹ ko di mimọ pe, awọn to wa lolu ilu orilẹede Naijiria, iyẹn Abuja ninu awọn eeyan naa ti n gba itọju nileewosan nla fasiti ilu Abuja ni Gwagwalada nigba ti awọn to wa nilu Eko n gba itọju nileewosan fun itọju awọn to ba ni ajakalẹ arun.

Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ninu atẹjade toun fi sita loju opo twitter tirẹ ṣalaye pe awọn ami aisan naa to farahan lara awọdn eeyan ọhun ṣi mọ niwọnba, wọn si n gba itọju bi o ti tọ ati bo ti yẹ.

Coronavirus in nigeria: Ọlọ́pàá ni yóò ma mú ẹnikẹni tó bá tàpa sófin ìjọba Eko

Ijọba Eko ti ko ọlọpaa sita lati ri wi pe awọn eniyan ko rin irin gberegbere lasiko arun Coronavirus yii.

Loju opo Twitter ipinlẹ Eko ni wọn ti fi lede pe ki awọn eniyan yago fun ara wọn ni ila mita kọọkan nitori naa ki awọn eniyan yẹra fun ibi ti eniyan to pọ ba wa.

Ijọba Eko ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko naa yoo ma fi panpẹ mu ẹnikẹni ti wọn ba ri ni ile igbafẹ, ibi ayẹyẹ tabi ibikibi ti ẹro pọsi lati ri wi pe arun coronavirus naa dẹkun.

Bakan naa ni wọn kilọ fun awọn eniyan lati ri pe wọn ko ju ogun eniyan lọ ni ibi ti wọn ba wa, ki eniyan ma pọju bo ṣẹ yẹ lọ ni ibikan.

Wọn rọ awọn eniyan ti wọn ba ni ikọ tabi inira lati mi, ki wọn lọ si ile iwosan fun iwosan to peye.

Awọn nọmba pajawiri ti ẹ le pe ni 08000CORONA, 08023169485,08033565529 tabi 08052817243.