Emir of Kano: Gómìnà Kaduna, El-Rufai fi ipò kejì dá Sanusi lọlá láàrin ọjọ́ méjì

Emir ilu Kano tẹlẹ, lamido Sanusi tun ti gba oye miiran lẹyin ti ijọba Gomina Abdullahi Ganduje rọ loye lọjọ Aje.

Lọjọ Iṣẹgun ni Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai yan an gẹgẹ bi ọkan lara awọn ajọ to n ri si ọrọ karakata ni ipinlẹ Kaduna,(KADIPA).

Lonii Ọjọru. ọjọ kọkanla oṣu kẹta ni Gomina El-Rufai tun fun Sanusi ni ipo mii.

Oludamọran Gomina lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Muyiwa Adekeye ṣalaye pe Sanusi ti di alakoso igbimọ alaṣẹ fasiti ipinlẹ Kaduna.

Sanusi rọpo Oba Alaye, Malam Tagwai Sambo to ti wa nipo naa lati ọdun 2005.

Adekeye ṣalaye pe Gomina El-Rufai fun Sanusi ni ipo ọhun nitori ipa to ti ko lori eto ẹkọ lorilẹede Naijiria.

Gomina El-Rufai dupẹ lọwọ Malam Sambo fun bi o ti gba pe ki Sanusi di alakoso igbimọ alaṣẹ fasiti ipinlẹ Kaduna tuntun ọhun.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna fún Sanusi ní ipò tuntun

Gomina ipinlẹ Kaduna ti yan Mahammadu Sanusi keji gẹgẹ bi ọkan lara awọn ajọ to n risi ọrọ karakata ni ipinlẹ Kaduna,(KADIPA).

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti fi lede wi pe wọn fẹ fi eyi ṣe atunto ẹka to n risi idagbasoke ọrọ aje ni ipinlẹ naa.

Wọn fikun wi pe awọn gbe igbeṣẹ naa nitori wọn mọ pe ipinlẹ Kaduna yoo fi ohun ribiribi kọ lara ọgbọn ti Sanusi ni ati oye rẹ nipa eto ọrọ aje.