Emir of Kano: Ganduje fún Aminu Ado Bayero ní ìwé ìyannisípò gẹ́gẹ́ bí Emir ìlú Kano

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ati moye yii jẹ, iwo n papa, iwo n na! Bayii lọrọ ri fun Emir ilu kano tuntun, Aminu Ado Bayero atawọn alatilẹyin rẹ, lẹyin ti Gomina Abdullahi Ganduje fun ni iwe iyannisipo nirọlẹ Ọjọru niluu Kano.

Aminu ni Emir ẹlẹẹkẹẹdogun ti yoo jẹ niluu Kano lapa ariwa orilẹede Naijiria.

Lọjọ Aje ni akọwe ijọba ipinlẹ Kano, Alhaji Usman Alhaji kede Aminu Ado Bayero gẹgẹ bi Emir tuntun ilu Kano lẹyin ti ijọba rọ Lamido Sanusi loye.

Emir Bichi ni Aminu tẹlẹ ko to di Emir ilu Kano lọjọ Aje, o ti rọpo Emir Kano tẹlẹ, Lamido Sanusi bayii.

'Fáàbàdà! Buhari kò lọ́wọ́ sí ìyọnípọ̀ Sanusi, e yé parọ́ kiri.'

Faabada! Aarẹ Muhammadu Buhari ko lọwọ ninu irọloye Emir ilu kano ana, Lamido Sanusi bii ti wulẹ o mọ.

Oludamọran pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu lo fọrọ yii lede loju Twitter rẹ.

Shehu ṣalaye pe ko si otitọ kankan ninu ahesọ ọrọ tawọn eeyan kan n gbe kiri pe ati yọ Sanusi nipo ko sẹyin Buhari.

Oludamọran aarẹ ni oṣelu lo wa nidi ọrọ tawọn kan n sọ pe Aarẹ Buhari mọ nipa bi ijọba ipinlẹ Kano ti rọ Sanusi loye.

Garba Shehu ni adura ni Buhari pe ifẹ Eleduwa nikan ni ko maa wa si imuṣẹ nigba gbogbo nipinlẹ Kano, ẹnikẹni ko wu ko wa lori itẹ gẹgẹ bi Emir ilu Kano.

Aarẹ Buhari ki awọn araalu Kano fun ifarabalẹ wọn ati bi wọn ti gba alaafia laaye lati igba ti ijọba Gomina Abdullahi Ganduje ti rọ Sanusi loye gẹgẹ bi Emir ilu Kan

Ààrẹ Buhari mọ̀ nípa ìyọnípò Sanusi Lamido II gẹ́gẹ́ bí Emir Kano-Kwankwaso

Gomina nigba kan ri nipinlẹ Kano Rabiu Musa Kwankwaso ti di ẹbi iyọninipo Emir Kano,Sanusi Lamido Sanusi, ru aarẹ Muhammadu Buhari.

Olori ẹgbẹ alatako naa sọ pe ijọba ipinlẹ Kano fun ara wọn n sọ pe aṣẹ ti wọn pa fawọn lati ọdọ ijọba apapọ lawọn tẹle lati rọ Sanusi loye.

O ṣalaye pe awọn to sunmọ aarẹ n sọ pe aarẹ Buhari kii da si iru awọn aawọ bayi ṣugbọn ti ọrọ ba kan ipinlẹ Kano,bakanna kọ ni ọmọ ti ṣe sori.

Kwankwaso sọ pe Buhari n da si ọrọ Kano.Nigba to yẹ ko sọrọ,gbogbo wa la ripe o dakẹ.Nigba ti ko ba si yẹ kodakẹ, a ma sọrọ.

Lati igba ti wọn ti yọ Sanusi ni ọjọ Aje,ijọba Buhari ko ti fesi si iṣẹlẹ yi.

Ṣugbọn ṣaaju asiko yi ni aarẹ ti sọ wi pe oun ko ni dasi ọrọ abẹle to n waye ni ipinlẹ Kano. Ile iṣẹ BBC ko ti ri aridaju lati fi sọ boya lootọ ni awọn nkan ti Sẹnẹtọ Kwankwaso sọ yi.

Lasiko ijọba Kwankwaso ni Emir Sanusi gun ori oye.

Lọwọlọwọ bayi,Emir Sanusi wa ni ipinlẹ Nasarawa nibi ti wọn le lọ lẹyin iyọnipo rẹ.

Kwankwanso ni ohun ibanujẹ lo jẹ fun ipinlẹ Kano nitori ọba alapọnle nile ati lẹyin odi ni Sanusi jẹ.Gẹgẹ bi ohun to sọ, o ni awọn ri aridaju pe ijọba apapọ mọ wi wọn gbe igbesẹ lati yẹ aga nidi Sanusi.

O tako ọrọ tawọn kan sọ wi pe lati igba ti Kwankwaso ti wa lori oye ni ijọba ti n kilọ fun Sanusi pẹlu bi o ti ṣe ma n sọ ọrọ ti ko fidimulẹ.

''Mi o fi iwe ikilọ kankan ranṣẹ si Emir Sanusi tabi nkankan to jọ bẹ''

BBC tun beere lọwọ rẹ nipa ẹsun tawọn kan fi kan awọn alatilẹyin Kwankwasiyya pe awọn ni wọn runa si wahala laarin Sanusi ati Gomina Ganduje.

Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ,Kwankwanso sọ pe ohun tawọn eeyan Kano n sọ ni pe inuEmir Sanusi ko dun si Ganduje nitori pe aarẹ ti ni ki wọn jẹ ki awọn to ba jaweolubori ninuidibo ṣe ijọba.

O wa bẹnuatẹ lu bi aibọwọ funEmir yi ti ṣe tabuku ba awọn eeyan ipinlẹ Kano.