You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun Accident: Ọkọ̀ àwọn olùjọ́sìn náà dédé yíwọ́ lọ kọ lu ògiri
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni lọọlọ yii ni pe eeyan mẹfa ti ku ninu ijamba ọkọ akero kan lowurọ ọjọ aiku.
Gẹgẹ bi awọn oniroyin ṣe sọ ọ, awọn to ba iṣẹlẹ naa rin n ririnajo bọ lati ipagọ adura awọn Kristẹni kan eyi ti wọn n pe ni Oke Maria Pilgrimage ni agbegbe Otan Ayegbaju ninu ọkọ ijọ Paul Catholic Church, Lagere Ile Ife.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ṣe ni ọkọ to n gbe awọn ero ọhun bọ lati ipagọ adura ti wọn ṣe lọjọ ẹti yiwọ to si lọ rọ lu odi kan lẹba opopona Ire/Eripa/Otan Ayegbaju/Ila eyi to si jẹ ki ọkọ naa da sinu koto.
- Èyí ni nkan tí a mọ̀ nípa ààrùn tó n pani ní Nàìjíríà tí kìí ṣe CoronaVirus, Lassa, tàbí Ebola
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Eko tẹ ọmọ ọdún 22 tó jẹ́ olórí 'bambam' f'ẹ́gbẹ́ òkùnkùn Berry Boys
- Àrá sán pa aboyún ìnàkí àtàwọn mẹ́ta míì tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láyé
- Ẹ má ṣe fàsẹ́yìn rára o lórí ikọ̀ àmọ̀tẹ́kùn - Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin rọ àwọn gomina
- 'Ẹ jọ̀ọ́, a ò fẹ́ gbọ́ òfófó ìròyìn mọ́ pé àbúrò mi gún bàbá àti ìyá mi pa, ó ti tó gẹ́!'
- Lẹ́yìn tó fi ọ̀bẹ halẹ̀ mọ́ ọ, ọkọ Magarita fi àáké gé e lọ́wọ́, kí ló ṣe tó bẹ́ẹ̀?
- Àwọn ológun ṣíná ìbọn pa Sọjà tó pa èèyàn 26 ní Thailand
Iroyin sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ aṣọbode ti de ibi iṣẹlẹ naa ti wọn si ti n gbe awọn to fara pa jade kuro ninu ọkọ naa pẹlu iranlọwọ awọn to n gbe ni agbegbe naa.
Lasiko ti iroyin naa wọle, o ti le ni eeyan mẹwaa ni o ti gbẹmi mi gẹgẹ bi awọn to n kọja lọ ṣe n ke bosi o.
Ọjọ ẹti ọjọ kẹjọ oṣu keji ni ipagọ adura naa waye eyi ti ọgọrọ awọn olujọsin korajọ fun adura ni Oke Maria to wa ni Otan Ayegbaju.