You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Christmas: Ìdí rè é tí Gómìnà Sanwo-Olu ṣe buwọ́lùú kí wọn tú ẹléwòn sílẹ
Gomina Babajide Sanwo Olu ti buwọlu iwe ofin meji eleyi to faṣẹ si itusilẹ awọn ẹlẹwọn mẹfa ati iyipada idajọ iku si ẹwọn gbere fawọn mẹta miran.
Sanwo- Olu sọ pe igbesẹ yi jẹ ọna kan gboogi lati fi ẹmi imoore han lasiko ọdun Keresimesi.
Lasiko to n kopa nibi ijọsin Keresimesi ni ṣọọsi Cathedral Church of Christ, ni Marina nilu Eko lo ti lede ọrọ yii.
Agbẹnusọ rẹ, Gboyega Akọsile naa fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ.
Akọṣile ni: ''Ohun to yẹ gẹgẹ bi orile-ede ni ki a fi ẹmi imoore han ki a si woye nkan to ṣẹlẹ kọja ninu ọdun yi.
O ni ki a si wo ọna taa fi ṣatunṣe ki a ba le jẹ ọmọ orile-ede to dara ju ti tẹlẹ lọ''
Akọsile sọ pe Gomina Sanwo- Olu ti tẹlẹ ohun ti ofin gbaa laaye lati ṣe ati pe ọwọ awọn to n dari eto idajọ nipinlẹ Eko ni itẹsiwajuọrọ naa kan tofi de ori adari awọn ẹlẹwọn naa.
Ninu awọn ẹlẹwọn to gba idande lati ri Bestman Dennar; Wasiu Jimoh; Augustine Opara; Folakemi Osin; Rebecca Danladi ati Njoku Ogechi.
Lara awọn ti wọn yi idajọ iku pada si ti ẹwọn gbere fun ni Muhammed Abdulkadir; Moses Akpan ati Sunday Okondo.