Electricity: Ìjọba àpapọ̀ f'ẹ́ já iná mànàmáná orílẹ̀èdè Togo àti Benin Republic nítorí gbèsè $7m

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹ lọ sanwo ina yin o! Ẹ lọ sanwo ina yin o!!

Ariwo tijọba apapọ Naijiria n pa le awọn to jẹ ẹ ni gbese owo ina niyi bayii o.

Amọṣa lọtẹ yii kii ṣe awọn ọmọ orilẹede Naijiria nijọba apapọ n ba wi, bikoṣe awọn ijọba orilẹede meji kan lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika.

Bẹẹni, ijọba apaps Naijiria ti jawe ikilọ ranṣẹ s'orilẹede Togo ati Benin Republic pe ki ijọba ibẹ tete san gbese ina ẹlẹntiriki ti wọn jẹ orilẹede Naijiria.

Hmmm... alaga ajọ apapọ ina manamana lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika, Usman Gur Mohammed ni orilẹede mejeeji yi jẹ Naijiria lowo ina to to miliọnu meje dọla owo ilẹ Amẹrika, ($7m).

Ọgbẹni Miohammed ni oun o le joye akotileta ti yoo maa yan awọn ọmọ Naijiria jẹ lori ọrọ ina ọba.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, 'Ọgọrun miliọnu dọla owo ilẹ amẹrika, ($100m) ni orilẹede Benin ati Togo n jẹ ni gbese owo ina nigba ti mo de ipo alaga ajọ apinna ọba Naijiria, TCN. Nibayii mo ti gba owo naa ku miliọnu meje dọla owo ilẹ Amẹrika, ($7m)."

Owo ina ti orilẹede Niger republic ni tirẹ n jẹ din diẹ ni miliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika, ($2m). A o si ni fi wọn silẹ. A maa ja ina wọn gẹgẹ bi a ṣe n ja ina awọn eeyan ni Naijiria nibi ni."

O ni ko soju aanu lọrọ ina ọba lilo ati pe ko ni si aaye fun awọn eeyan lati maa lo ina ẹlẹntiriki orilẹede Naijiria lai san owo rẹ.

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ lori rẹ?

Ni kete tawọn ọmọ Naijiria gbọ ọrọ yii, oniruuru esi ni wọn ti n fọ lori rẹ.

Awọn ọmọ Naijiria kan n tara ni pe inu awọn ko dun si iroyin naa nitori pe o ni ohun ti oju awọn ọmọ Naijiria to jẹ owo diẹ lasan n ri lọwọ awọn oṣiṣẹ amunawa eleyi to fihan pe ijọba apapọ kii ṣe iru rẹ fun awọn ilẹ okeere to jẹ ẹ ni gbese owo ina.

Bakan naa lawọn kan kọminu pe orilẹede Naijiria ko lee pese ina to duro deede fun awọn eeyan rẹ to jẹ oninkan, ṣugbọn o lee maa pese ina ologeere fawọn ti ilẹ miran to si jẹ pe lẹyin o rẹyin wọn ko ni san owo ina naa.