You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Grammy Award: Burna, Sunny Ade, Femi Kuti ni àwọn akọrin Nàìjíríà tí orin wọ̀n gbà ìdánimọ̀
Ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu, bẹẹ lọrọ ri fun ilumọka akọrin takasufe ọmọ Naijiria nni, Burna Boy, ẹni to ti kọrin rẹ debi idanimọ Grammy bayii.
Loju opo ayelujara awọn alakoso eto ami ẹyẹ Grammy, ni wọn ti kede pe orukọ Burna Boy wa ninu akọsilẹ orukọ awọn eeyan ti wọn n woye fun ami ẹyẹ.
Isọri ami ẹyẹ ti wọn si fi orukọ Burna si ni ami ẹyẹ fun orin agbaye to fakọyọ julọ (Best World Music Album), orukọ awo orin rẹ to gbayi ti wọn fi faa kalẹ ni African Giant.
Ikede yii ti wa n mu ki awọn ọmọ Naijiria, akọrin ati awọn ololufẹ rẹ maa kan sara si loju opo Twitter rẹ pe o ku oriire.
Awọn akọrin miran ti wọn ti fa kalẹ fami ẹyẹ Grammy ṣaaju:
Angelique Kidjo lakọrin kan to ti gba ami ẹyẹ ni ipele ti wọn fa Burna Boy kalẹ fun yii. Lọdun 2016 si lo gba ami ẹyẹ naa.
Bi a ba ni ki a wo awọn akọrin lorilẹede Naijiria ti wọn ti fa kalẹ fun ami yii, wọn ṣe bii ẹni pọ diẹ.
Lara wọn la ti ri King Sunny Ade ti wọn fa kalẹ lẹẹmeji ọtọọtọ lọdun 1983 fun awo orin rẹ ti wọn pe ni 'Synchro System'.
Bẹẹ ni wọn fa awo orin rẹ miran 'Odu' kalẹ lọdun 1998 ni isọri ami ẹyẹ ti Burna Boy n dije fun bayii.
Awọn akọrin miran to tun ti kọrin gba idanimọ yii ni:
- Femi Kuti
- Wizkid
- Sikiru Adepoju
- Chamillionaire
- Sade Adu
- Kevin Olusola