World Mental Health Day: Báyìí ni o ṣe lè sá fún èdì tí àìsàn ọpọlọ bá gbé súnmọ́ ẹ

Kìí ṣe gbogbo ẹni to fẹ fo latori afara odo lo wu lati ku. Wọn kan fẹ mọ boya eeyan kan le wa to nifẹẹ wọn ni."

Eyi lohun ti Kevin Hines to gbiyanju lati fo sinu odo ko le gba ẹmi ara rẹ ni Golden Gate Bridge ti San Francisco ninu oṣu kẹsan ọdun 2000.

bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ eniyan lo ri i lori afara ko to gbiyanju lati pa ara rẹ - koda onirinajo igbafẹ kan ni ko ya oun ni fọtọ.

Ko sẹni to mọ pe o ni iporuru ọkan tabi to bi i lere pe ki lo ṣẹlẹ̀. Nitorinaa, lo ba di gbi ninu odo.

Lọna ara, o ye iku lọwọ iwọn metre marun omi to jin ṣugbọn eniyan o le ni eniyan ẹgbẹrun meji din ni ọọdunrun lo ti gbẹmi ara wọn nipa bibẹ somi latori afara lati igba ti wọn ti fi odo Golden Gates ọhun lọọlẹ ninu oṣu karun un ọdun 1937.

Odo yii wa lara awọn ibi to gbajumọ ju tawọn eeyan ma n lo lati lọ gba ẹmi ara wọn.

Fun idi eyi, Kevin ni ikọ tirẹ to ma n wa si ori afara naa lati foju ganni ati lati doola ẹmi awọ́n to ba bẹ dinu omi nipasẹ ilana ranpẹ.

"Awọn Angẹli"

Lọdun 2018 nikan, eniyan igba o le mẹrinla to gbiyanju lati bẹ somi iyẹn tumọ si eeyan kan lojojumọ.

Pe eeyan mẹtadinlọgbọn pere lo ba a lọ lasan to lati gboriyin fun iṣẹ awọn agbofinro atawọn ayọnda ṣiṣẹ bii ti Mia Munayer ati Kevin Briggs.

Ọlọpaa lawọn mejeji bi o tilẹ jẹ pe Briggs ti fẹyinti lẹnu iṣẹ, awọn ayọnda ṣiṣẹ Munayer, Bridgewatch Angels ni wọn ms n saba pin si iṣẹ nibẹ lati ran awọn to jẹ ọga wọn lọwọ.

Ilera to ni ṣe pẹlu ọpọlọ

Ajọ eleto ilera agbaye ṣe iṣiro rẹ pe o sunmọ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin eeyan to ku nipasẹ gbigba ẹmi ara wọn.

Bakan naa, ibudo orilẹede Amẹrika to n boju to itju aisan na ni akọsilẹ to sọ pe ẹgbẹrun mẹtadinlaadọta eeyan lo gba ẹmi ara wọn nilẹ amẹrika lọdun 2017 eyi si ni ohun to n ṣokunfa iku awọn ara Amẹrika larin ọdun mẹwaa si mẹrinlelọgbọn.

Gbigba ẹmi ara ẹni lee nidi ṣugbọn o maa ni ibaṣepọ to nipọn pẹlu ilera ọpọlọ paapaa iporuru kan.

"Ida aadọrun awọn to gbẹmi ara wọn lo ti ni itan aisan to ni ṣe pẹlu ọpọlọ ri tabi iṣoro fifi ipa mu ni lasiko iku wọn

Ohun ti awọn Bridgewath Angels n se ni lati dena gbigba ẹmi ara ẹni.

"Bi a ṣe n ṣe e"

Emi atawọn akẹgbẹ mi n ṣe idanilẹkọ kan wọn si fi fidio BBC nipa rẹ han wa.

Nigba naa mo mọ pe mo ni lati ṣe nkan ti yoo dẹkun iku awọn eniyan.

Eyi lo mu ko da ẹgbẹ awọn Angẹli silẹ ti wọn si ti n paraa odo Golden Gates lati dun 2011 paapaa lawọn ọjọ pataki bii ayajọ ọjọ awọn ololufẹ tabi ọjọ keresi - wọn si kọ wọn bi wọn ṣe le ba ẹnikẹni ti wọn ba ro pe o ni iporuru ọkan sọrọ.

"A maa n tẹti si awọn eniyan, a si maa n gbiyanju lati rii pe awọn yẹn sọrọ. O ṣe pataki lati ma fọwọ kan wọn ju ki wọn rii pe wọn n da wọn lohun".

"Nigba mii mo maa fọrọ wa awọn eeyan ti mo doola lẹnu wo bii ọrọ to kan gbogbo eeyan. ki ni mo sọ to dara abi ti ko dara?".

Pẹlu ọgbọn, Briggs a yi awọn eeyan to le nigba lọkan pada lati gun ori irin afara pada lati ma ko somi mọ. Ko ju ẹẹmeji lọ ti ọgbọn rẹ yii ja a kulẹ ti wọn ko dahun.

"Awọn ijakulẹ yii si leeyan maa n ranti ju awọn eyi to yọri teeyan ti ṣe lọ".

Ọ̀rọ̀ àwọn tó jàjà bọ́

Diẹ lara awọn tori yọ bọ sọrọ lori bi wọn ṣe kabamọ pe wọn pinu lati lọ bẹ sinu omi ni kete ti wọn gbera lori afara.

"Orirun iku ni afara yẹn," Kevin Hines to fẹ bẹsomi ninu oṣu kẹjọ ọdun 2000 sọ fun CNN, ṣugbọn mi o ba ma ṣe bẹẹ bi eeyan kan ba ba mi sọrọ".

"Bí o bá rí èèyàn kan nínú ìrora, ipa rẹ ni láti tọ ẹni naa lọ ki o sì bá a ni gbolohun, rii pe wọn la ohun si ọ ki o si ri i pe wọn s ohun ti o wa lọkan wọn"

"O lee jẹ ohun elo fun ayipada ọkan".